Ojo malegbagbe lojo ti Balocool sayeye ojo ibi e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 27, 2017

Ojo malegbagbe lojo ti Balocool sayeye ojo ibi e

Titi di bi a ti n koroyin yi lawon to mo iyi gbajumo onisowo nni, Alaaji Adelusi Balogun Shittu, eni topo mo si Balocool si n fi ateranse ranse sii lati kii ku ayeye ojo ibi odun marunlelaadota, 55years to se logunjo osu yi, iyen June.

Balocool
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni ojo malegbagbe lojo naa je fokunrin naa nitori tawon ojogbon ateeyan pataki laarin awujo ni won wa a ba okunrin topo mo si Balocool yi sayeye naa nile e to wa ni Osogbo, ipinle Osun.

Omo bibi ipinle Ekiti nigba to n soro lojo naa dupe lowo Olorun Allah fun ti aanu to ri gba nitori pe opo ni won pe odun naa to je pe won ko tii ni nkan toun ti ni, tawon min in si ti ku, sugbon o ni kii se tigberaga bi ko se oore ofe Allah.

Okunrin oniwa irele Balocool so pe opo ojo lo ri ro, ti ile si ti fimu nitori pe awon ipenija ati adojuko toun ba pade nigbesi aye oun, paapaa nigba toun wa ni kekere ko see fenuso, sugbon ola Olorun lo gbe oun duro di asiko yi.

Alaaji Shittu tun so pe lara oore ofe toun ri gba loun naa ti n saanu awon eeyan pelu nnkan ti Adeda foun. O so pe bo tile je pe isoro ti orileede yi koju laarin odun to koja si asiko yi, fee mi oun naa, sugbon sibe, Allah si gba akoso, tenu oun si gba ope.

Bakan naa lo wa gbawon eeyan lamoran pe ki won maa lo anfaani ojo ibi won lati fi dupe lowo Olorun Oba nitori pe Oun nikan lo le fun eeyan ni anfaani lati ni emi gigun pelu alaafia.

Bee lo so pe ki won maa gbiyanju lati maa saanu awon to ba ye, nitori pe bi eni to n ba Olorun dokoowo ni aanu ri, ko si seni to ba Olorun dokoowo to padanu ri.

Lojo naa la gbo pe awon agba nidi esin Islam tokunrin naa n se gbe akanse adura kale fun un nitori ipa to n ko lawujo paapaa lati gbe esin Islam laruge.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI