Won ni Musibau paro mo awon olopaa nitori iku aburo e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 10, 2017

Won ni Musibau paro mo awon olopaa nitori iku aburo e

Sugbon okunrin naa ni iro ni

Kani awon araalu ko tete ba Arakunrin kan ti won poruko e ni Musibau Sabitu, eni ogota odun rawo ebe sawon olopaa ipinle Ogun ni, lori bi won loo se paro mo won latari iku aburo e, Kehinde Sabitu ni, ohun ta n ko yi ko ni a o ba maa ko, nitori pe die lo ku kawon olopaa so o satimole lori esun to fi kan won yi.

Musibau Sabitu
Bo tile je pe awon olopaa gbo ebe naa, ti won ko si je ki okunrin naa de ogba won depodepo pe o maa sun atimole won, sibe awon eeyan naa si n so okunrin naa lowo lese nitori awon nnkan ti won lo so mo iku aburo e, Kehinde ti asiri e sese tu si won lowo.

Gege bi AWIKONKO se gbo, lori eto kan nileese redio taa foruko bo lasiri to wa niluu Abeokuta ni won lokunrin naa gba loo to si loo ke gbajare pe kawon araalu gba oun, nitori iwa tawon olopaa hu lori bi won se fawon meta sile ninu awon toun fesun kan pe won lowo ninu iku aburo oun, o ni biigba ti won gbabode foun ni.

Iwadii fi ye wa pe ni nnkan bi aago mewa ku iseju meedogun ale ojo ketadinlogun osu kerin odun yi, iyen lojo Monde Ajinde nisele naa waye labule kan ti won n pe ni abule Owu, eyi to wa nijoba ibile Odeda, nibi tawon odo agbegbe naa ti n sayeye ti won maa n se lodoodun, ti won pe ni Carnival.

Won ni Kehinde ti won fikuu aitojo yii pa lo fun won ni ero amohundungbemu ti won lo lojo naa peluu jenereto, awon odo yii ni won dawo ra epo petiroolu si jenereto ti won loo naa pelu adehun pe ibi ti epo naa ba ti tan si, ni ariya naa pari mo.

AWIKONKO gbo pe bi Kehinde se gbe jenereto naa kale ti faaji n loo, loun ti loo sun sori aga kan ni ero pe ti won ba setan, oun yoo wole loo sun. Oro naa yipada nigba ti won ni Egbon e to n je Musibau de, to si lo sibi ti jenereto wa lakoko tawon yen n jo lowo, to si loo yo okun ina legbe jenereto naa, iyen gan lo da surutu sile.

Ariwo pe kilo sele gan, ta lo pa jenereto, lakoko ti faaji n wo ara won, ibeere ti won lawon odo yen n beeere niyen, ti won si so dija mo ara won lowo, to di pe won ju okuta soke.

Igbe wahala to n sele yi ni won loo ji Kehinde eni odun mokandinlaadota nibi to sun si, to si bere si nii salo, ko to di pe won le, ibi ti won ti n le ni won lo ti yo igi, to si fo mo okan lara awon odo to n je Abiodun Hassan lori legbe oju.

Iyen ni won loo ja igi naa gba pada lowo e, to si fo mo on lori, laimo pe iso wa nibe, to si subu lule, to daku ti won si sare gbe loo si osibitu FMC to wa ni Idi Aba nibi to dake sii. Bi isele naa se waye ni won ni Musibau egbon e yii lo so fawon olopaa to wa ni Odeda ti won si mu awon merin.

AWIKONKO gbo pe esun apaayan ni won fi kan awon merin towo te, awon merin ti won mu ni Biodun Hassan omo odun merindinlogbon, Latif Sonola, Kazeem Olaibe ati Monday Faseri, ti won si se iwadii lori iku Kehinde. Ohun tawon olopaa so ni pe Abiodun Hassan to fogi mo Kehinde jewoo pe oun loun fogi mo ati pe oun ko mo pe iso wa lara igi naa.

Iwadii ti won se yii lo muu ki won fawon meta yooku sile, eyi gan an ni won lo fariwo ti won ni Musibau n pa pe awon olopaa ti gbabode nitori awon ti won fi sile, o ni won fo igi mo oun naa legbe won si gbodo jejoo. Idi niyii ti won lo fi gba ileeese redio loo to loo pariwo.

Bo tile je pe won lawon to n seto naa ko sewadii oro naa daadaa ki won si gbo tawon olopaa ko to di pe won gbe safefe lojo naa, ohun lo wa da wahala sile to mu ki agbenuso fawon olopaa, Abimbola Oyeyemi naa fi gba ori eto naa loo to si loo salaye boro naa se je.

Nibe ni awon olopaa ti fesun kan Musibau pe se lo loo n dunkoko mo awon tawon fi sile leyin tawon pari iwadi won pe ki won loo mu milionu meta naira wa, ti won ko ba fee sejo, ati pe o fee foku aburo e yii maa powo ni.

Oku Kehinde Sabitu
Oga olopaa naa so pe idi tawon fi fawon eeyan meta naa sile ni pe eni to paayan ti jewoo pe loooto loun se, tawon si ti fi pamo nibi to ti n jejoo lori esun apaaayan sugbon awon tawon fi sile naa ko mo nnkankan nipa e.

Nigba tawon araalu wa rii pe iro Musibau n pa, kii se pe nnkan tawon olopaa so nipa oun je iro, ni se ni won so pe ko toro aforiji ti won si n soko oro sii. A fi baa tun se gbo pe ni ojo keji ti Kehinde ku ni okunrin yii atawon kan ninu ebi e loo ta oko oloogbe naa.

Iyalenu lo si je fun wa pe won ni ara eni ti won ta oko naa fun ko ya latigba ti won ti taa fun un, ti won ni okunrin naa so pe oun ri Kehinde to ni oko naa loju oorun, to n yo oun lenu, ni bayii, a gbo pe won ti gbe okunrin naa kuro nile yii loo si orile ede won, Kutonu fun itoju.

Nigba ti Musibau n ba oniroyin wa soro ni nnkan bi aago meji osan ojo Abameta Satide yi lori awon esun ti won fi kan an naa, o ni Mama oun ti so pe koun maa so nnkankan lori e. Bee lo ni loooto lawon ta oko aburo naa ni egberun lona ogoji naira peluu awon omo e sugbon oun ko ba won tewo gbowo naa.

O loun ti soro lori redio lojo tawon lo pe oun ko ba enikeni duna-dura owo rara, atipe oun ni eleri to po, sugbon awon eleri oun foju oun gun igi lojo toun lo sori redio, won ko yoju.

Sugbon nnkan tawon eeyan naa so ni pe owo Musibau gan ni iku aburo e ti wa, nitori pe ka ni ko loo yo okun ina nibi jenereto naa ni nnkan to sele lojo naa ko nisele, ati pe epo to wa ninu petiroolu naa ti fee tan tele amo ti o loo fibinu da wahala sile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI