Ko rorun keeyan padanu ninu idibo - Omilani - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 10, 2017

Ko rorun keeyan padanu ninu idibo - Omilani

Ko seeyan to ko mi nise sorosoro, Olorun lo funmi lebun e...
Ko ye ka maa lo sori redio lati bu ara wa, ailekoo ni...

Omilani
Alaga tuntun ti won sese dibo yan fegbe sorosoro Freelance and Independent Broadcasters’ Association of Nigeria, FIBAN eka tipinle Ogun, Komureedi Olufemi Omilani Iyanda soro nipa idibo to gbe e wole gege bi alaga tuntun, bee lo tun soro nipa irin ajo e sidi ise naa. O so nipa awon isoro ati ipenija to koju. E kaa bi iforowero naa se lo.

AWIKONKO: E je ka mo yin lekunrere.
OMILANI: Olufemi Omilani Iyanda loruko mi topo mo si ‘E ma ran Baba n’Ifo.

AWIKONKO: A kii yin ku oriire tuntun, nje e ti e le so fun wa bi e se bere igbesi aye yin, ki e too di sorosoro, debi ti e fi darapo mo egbe naa?
OMILANI: Awon Yoruba ti so pe ‘okun ko nii gun titi ko ma nibi to ti wa’, irin ajo mi sidi ise sorosoro je nkan ti mo ni itara fun nitori pe o ti wun mi lati kekere. Ti m ba fee so pe iye odun ti mo ti n se e loni seresere, ti won ti n pe mi fun MC, odun 2002 ni. Nigba yen lemi naa maa n mu awon oja kan, ti maa si se ipolowo e llati fin ko ara mi, ti maa fi mo bo se maa ri leti tawon eeyan ba gbo. Sugbon nigba ti mo wa jade ileewe girama, mo ni oore ofe lati gba imoran lati odo aburo baba mi kan, eni to so fun mi pe ki n lo kekoo nipa ise igbohunsafefe nileewe giga. Olorun seun, mo ri anfaani latii wo ileewe gbogbonise ti Moshood Abiola nibi ti mo ti loo ko nipa ise iroyin ati igbohunsafefe fodun merin, nibe ni imo yen tun ti de sii. Sugbon ti m ba so pe odun ti mo wonu ise yi gangan, odun 2010 ni, odun keje re e.

AWIKONKO: Leyin ti won kede yin gege bi alaga lawon awuyewuye ati wahala kan dide, to mu kawon kan so pe awon ko segbe mo nitori pe eyin le wole. Ona wo le fee gba lati pe awon eeyan yi pada, ki ife si le joba ninu egbe FIBAN?
OMILANI: Ko rorun keeyan padanu ninu idibo, eyi lo je ki n ki oga mi Adeyinka Adegbite wi pe won lo okan akin lati tete gba wi pe bi Olorun se fe ko ri lo ri. Ko si kiru e ma sele pe ki inu ma bi awon alatako paapaa to ba je pe die ni won fi la ara won. Ko si kinu ma bi awon kan nitori pe o han sawon eeyan to wa nibe lojo naa pe ko si awuruju ninu eto idibo yen, sugbon wi pe awon kan fe e kuro ninu egbe FIBAN, mi o tii gbo, enu yin ni maa ti koko gbo, sugbon mo mo pe inu awon kan ko dun nitori pe awon ti won fe ko wole ko lo wole. Nii sin yi, mo ti d’alaga fun gbogbo omo egbe FIBAN nipinle Ogun. Ko si enikan ninu egbe paapaa ninu aawon ti won tako mi ti mi o ni ibasepo to dan monran pelu won. bi mo se n ba ayin soro yi, mo ti pe opolopo ninu won lori aago, to fi mo mama wa Yeyeluwa Ibiyemi Ajadi, MC Murphy, Goke Babalola, Olumide Awolowo atawon mi n ni mo ti bara soro lonii lati dupe lowo won.

AWIKONKO: Ki le fee so pe o je gege bi ipenija ti e ba pade latigba naa titi digba ti won fi dibo yan yin gege bi alaga tuntun?
OMILANI: Ipenija po repete ti mi o le ka tan, sugbon awon oloyin a maa so pe “it is not how far, but how well”, iyen ni pe kii se bi o ti pe to, sugbon nkan ti a ti gbe se. nigba ti mo bere, mo bere pelu ileese radio OGBC 2 lori eto kan ti won n pe ni ‘Lawuujo Eranko ati Eye’. Ona ti mo gba fi gba eto yi nigba yen, o ni awuyewuye die ninu nitori pe oga mi, Idowu Taiwo topo mo si ‘Ode Aperan’ lo n se e tele, sugbon awon nkan to sele nigba naa lo je ki won gbe eto yen fun mi. Olrun lo tete ba wa pana awuyewuye to dide nigba yen. Ipenija akoko ti mo koko koju niyi, sugbon ti e ba wo ajosepo to wa laarin emi ati Idowu Taiwo bayii, o ju tomo tiya lo. Eleekeji ni pe nigba naa lohun, Ajebo ni ileese redio OGBC wa, to je pe ti m ba pari eto tan, ese ni mo maa fir in latibe de ile mi to wa ladugbo Elite ti mo n gbe nigba yen. Aimoye nkan lo ti sele, sugbon aanu Olorun ni mo ri gba. Owo ta n gba nigba yen ko to nkan, ti a si n fori ti titi t’Olorun fi gbakoso lojo oni.

AWIKONKO: E daruko Idowu Taiwo gege bi oga yin, sugbon opo awon eeyan ro pe Kolawole Adejojo Kasnaty ni oga yin, e tan imole si daadaa fun wa.
OMILANI: Ti m ba daruko oga nidi ise ti a n se yi, nkan meji lo tunmo si, akoko ni pe enikeni teeyan ba ti ba niwaju nidi ise kan, yala o koo eeyan nise tabi ko ko eeyan nise, oga lo je. Eni to ba tun koo eeyan nise yen, to fi ona han eeyan, oga eeyan ni. Eni teeyan ba tun wa n wo awokose e lati fi se iwahu, oga naa lo tun je. Sugbon e je ki n laa mole fun un yin pe ko seeyan kankan to ko mi nise sorosoro, Olorun lo funmi lebun e lati kekere ki n to lo sileewe e, ti mo si kekoo gboye. Idi ti mo fi so pe oga mi Idowu Taiwo ni pe, oun lo bo bata ti mo kese bo to fi di nnkan tawon eeyan fi mo mi lonii, nitori pe eto Lawujo Eranko ati Eye lawon eeyan koko fi mo mi ko too di pe won bere sii gbo mi lawon ileese redio to ku. Se e wa ri ti Kolawole Adejojo Kasnaty ‘olohun agberin ti n fa gbogbo eti mora, a seto bi eni tori e yato’ ti e daruko yen, o je enikan to n’ife mi pupo, mi o si le so pe idi to fi feran mi niyii. Ona ti mo gba wonu ise sorosoro yato nitori pe eto Lawujo Eranko ati Eye je eto ise iwadii ijinle akaasile (documentary programme) lo je. Ti ki ba a se Kasnaty, mi o ba ti ni le seto min in to yato si irnkerindo ati oro eranko. Ni se lo maa je ki n da duro soju kan, sugbon Kasnaty lo je ki n mo pe ona kan ko woja, ki n tun je kawon eeyan mo pe mo le se eto ariya (entertainment programme). Nnkan ti mo n so ni pe Kasnaty lo fona eto ariya han mi, to si je ki n mon on daadaa, to tun ko mi lawon ona lati fi ise yi jeun, eyi ti ko ye mi tele, nitori pe lawon igba kan, mo ro pe mo ti mo ise yi lai mo pe mi o mo nkankan. Ti won ba n beere pe tani oga mi ti mo n wo awokose e nidi ise sorosoro, Kolawole Adejojo Kasnaty ni.

Alaga FIBAN
AWIKONKO: Eto Lawujo Eranko ati Eye ti e se yi, awon eeyan gba pe eni ti kii ba se ode ko le mo ijinle nipa awon eranko ti e maa n mu wa lose-ose, ati pe eni to ba loogun-abenu-gongo lo se e, abi ba wo ni?
OMILANI: Hmmmm! Nkan ti maa koko so ni pe ise teeyan ba je akosemose nidi e, tigbo ba di gaga, to di gaga, olode gbodo f’ada e yo. Eni to ba je akosemose nidi ise to n se, ti nkan ba fee wo, o ni lati ona to le gbe gba lati fi ri ojuutu si. Yato si t’oogun, opolopo awon eeyan lo maa n ro pe ise eranko ni mo loo ko nileewe, kii se be, ise igbohunsafe (Mass Communication) ni mo loo ko nileewe, sugbon won ko wa lati se ise iwadi ijinle (Research), nnkan ti mo se niyii ti mo fi bara mi nidi ka maa wadii nipa eranko ati eye. Mo ni awon ode to je pe won mo nipa eranko ati eye, awon ni won maa n fun mi loye. Mo maa n tori eto yi lo sipinle Ondo, Osun, Oyo, bee ni mo maa n lo kaakiri ipinle Ogun bii Ewekoro, abule mi Elere Adubi nibi ti mo mo pe awon ode wa daadaa, ti won si maa n salaye nkan ti mo ba ba lo fun mi. Opolopo igba ni mo maa n lo si Zoo nibi ti won ti n sin awon eranko lorisirisi lati loo wo bi won se n se. Ati pe aye tun ti waa lu jara bayii, aimoye nkan leeyan le ri lori ero ayelujara intaneeti. Iwadi ti a ba gba kaakiri la maa n ko jo po lati fi seto. Nipa ti oloogun de, ati eni to loogun, ati eni ti ko ni, Olorun ni kan lo n so eda, sugbon opo eeyan ni ko nii gbagbo ti m ba so pe mi o loogun, sugbon mo ni Olorun.

AWIKONKO: Gege bi alaga tuntun fegbe sorosoro, nje e ti e ti ni lokan lati di alaga egbe yi tele?
OMILANI: Beeni. Nkan to sele ni pe lopolopo igba leeyan maa n ni ero ojo iwaju sile, sugbon ti nkan maa n yi pada. Eeyan le ro pe oun fe se nkan lodun to m bo, sugbon ti Olorun a so pe ose to m bo ni, teeyan o si ni mo. Olorun lo maa wa gbe awon eeyan alaanu dide lati le keeyan tete ri n kan to fe gba. Ipo naa ti wa lokan mi lati ojo to ti pe, wipe tasiko ba to, mo maa dije dupo alaga egbe yi, sugbon ti mi o mo pe kiakia ni. Nigba to bere aarin awon meji lo ti bere, iyen Adeyinka Adegbite Omo Baba Tisa ati Akinyemi Olatoye, Alawiye, awon mejeeji ni won jo n ja dupo yi. Sugbon nigba ti mo woo titi, nitori pe mi o le wa nibi meji leekan naa, mo wa fara mo odo Alawiye lati sise fun fawon idi kan tabi omiran, sugbon kii se pe mo n ba Omo Baba Tisa ja. Nigba to ya ti orisirisi aheso bere sii jade nipa Alawiye, lo fi so pe oun ko se mo, koro naa ma baa le ju bo se ye lo. Nigba toun si ti so pe oun ko se mo, ko see se lati ma so pe kelomiran ma tun jade ninu egbe oselu ti wa, eyi lo fa a tawon agbaagba majeobaje fi woye pe ta ni won tun le lo lati gbapoti idibo yi, ni won fi wa a fimo sokan lati gbemi dide. Won ni Alawiye kowoje, o ti sejoba ri, sugbon Omilani ko kowoje, bee ko sejoba, e je ko lo dan an wo. Awon oga wa bii Omodo Agba, Tantala atawon kan lo ni ki won lo Omilani. Nigba ti won fi lo mi, emi naa koko ro o, sugbon nigba to je pe nkan to ti wun mi tele ni, mo gba lati se e. igba yen lo sese wa a di nkan temi ati oga mi Omo Baba Tisa sese wa fa, ti Olorun si je ki n gbegba oroke.

AWIKONKO: Ki wa le le so gege bi ipenija tabi adojuko nigba ti e pinu lati jade dupo yi?
OMILANI: Aimoye ipenija, nitori pe nigba ti won bere sii so pe Alawiye ko da a, o kowo je, ti gbogbo e si han si Olorun pe omoluabi eeyan lokunrin yi, to fi di pe emi naa jade, orisirisi awuyewuye jade nipa temi naa. A se ose FIBAN ti mo si wara lara awon igbimo to sagbateru eto naa, sugbon leyin lawon kan toro ko ye e bere sii gbe e kaakiri pe se la fi eto yen kowoje. O gba mi lopolopo akoko lati le yi okan awon eeyan pada pe beeko loro naa se ri. Leyin eyii, ka too se idibo, a gbodo se ayewo kan toloyinbo n pe ni screening daadaa, sugbon kayeefi lo je pe lojo ayewo yii, iwe esun (petition) bii merin lawon kan ti ko lati fi tako mi, wi pe a fi ki won ja mi, mi o gbodo dupo, won ni mo kere, won ni mi o tii pe ti mo wonu egbe sorosoro. Nigba ti Olorun maa gbe ise e dide, lawon igbimo eleto idibo wa so pe ki won kuku ja awa mejeeji, sugbon nigba to ya tawon agbaagba tun da si, won ni ki won fi wa sile.

AWIKONKO: Ohun taa gbo ni pe eni kan ti e pe ni oga yin, iyen Kasnaty ko fara mo o pe ki e jade dupo alaga yi, ti a si tun gbo ti won ni e so pe kii se oga yin mo, se looto ni abi aheso lasan?
OMILANI: E ma simi gbo o, mi o figba kan so pe Kolawole Adejojo kii se oga mi, oga mi ti mo n wo awokose e ni. Nnkan ti mo n so ni pe ko seeyan to ko mi nise yi nitori pe lakoko naa, ebun ti Olorun fun mi ni. Eleekeji ni pe mo tun lo sileewe lati lo ko nipa e. sugbon ko si eeyan se maa lo sileewe to, ti ko ba se nkan toloyinbo n pe ni practical, o n tan ara e ni. Ki emi ati Kasnaty to o pade lati mo ara wa, mo ti n seto lori afefe, o ti le ni odun meji. Lori eleekeji pe ko fara mo ki n di alaga, bee ko loro se ri. Ki n to jade dupo yi, Kasnaty ti wa pelu Omo Baba Tisa, o si da keeyan je omoluabi, ki won mo eeyan gege bi eni toro e kii yi pada. Ko ni bu iyi kun Kasnaty nigba to ti wa pelu Omo Baba Tisa latile, ko tun wa a pada leyin e niggba to ti seleri lati sise fun un. Oro oselu ni, kii se nkan babara lati so pe eeyan ko gbaruku ti enikan, rara. Bi tun se wa a di alaga yi, ateni to fowo si mi, ateni ti ko fe mi, alaga won ni mo je, ti mo si gbodo bawon fi ife lo. Kasnaty ko fe e ba omoluabi e je, nitori pe o ti wa nibi to wa ki n to o jade.

AWIKONKO: Ki e to o di alaga le ti n ba Kasnaty seto lori redio tawon eeyan si mo, sugbon ni bayii, nje e tun si le lo maa ba Kasnaty seto bii ti tele gege bi alaga?
OMILANI: Ibeere yin yi pami lerin pupo. Oro alaga tabi kii soro alaga, lati odun 2013 ni Olorun ti je ki oro emi ati Kasnaty ye ara wa, ko da, ife to wa laarin wa ju tomo atiya lo. Aimoye igba ni Kasnaty maa n pe mi lati sadura fun mi, to si maa n so pe boun se fe ko ri foun nit ko ri fun emi Omilani. Ko si ariyanjiyan ninu pe Kasnaty nife mi. Ko di alaga tabi mi o d’alaga, ko din ajosepo to wa laarin emi ati Kasnaty ku, ko tunmo si pe a o ni jo seto mo.

AWIKONKO: Nigba ti ajo eleto idibo kede yin gege bi alaga tuntun, bawo lo se ri lara yin?
OMILANI: Ko seni to maa dupo, to si maa bori ti inu e ko nii dun. Nigba ti eto yen n lo lowo, nkan ti mo koko ro ni pe mi o nii wole pelu awon nkan ti mo n ri, okan mi ti bere sii seye meji, sibe mo duro deede, okan mi o min, digbi ni mo duro bii kukute oju ona. Latile ni mo ti mo pe idibo yi kii se nkan tenikan maa ri pe ogorun loun fi la enikeji e, mo ti woo pe ko le ju ibo meji tabi meta lo. Mo ti so fawon taa jo wa ninu egbe oselu pe tipatipa lenikan maa fi fibo meji la enikeji e. Ibo mefa ni mo fi jawe olubori. Inu mi dun gan an nigba ti won kede pe emi ni mo wole. Inu mi dun kii se pe tori mo ti di alaga, sugbon inu mi dun nitori ti mo ti rii pe awon erongba rere ti mo ni lokan lati se gege bi alaga fee wa si imuse. Inu mi tun dun nitori pe lesekese ti won so pe emi ni mo jawe olubori ni oga mi Adeyinka Adegbite ti dide lati diro mo mi, to si ba mi yo, o tun gbadura fun mi. eyi tun mo si pe o gba pe idibo yen lo daadaa, o si fowo si.

AWIKONKO: Gege bi alaga tuntun, ki ni nkan akoko ti e fee koko se?
OMILANI: Nkan akoko ti mo fee se ni lati so gbogbo omo egbe FIBAN di eyokan ki ife si joba. Mo ti pe opo awon agbaagba paapaa awon ti mo ro pe won si n binu ni mo tun ni lokan lati loo ri won nile, ka si jo so asoyepo, ki ajosepo to danmoran si le wa nitori awon oloyinbo ni ‘a house that is divided against itself can not stand’, iyen ni pe ile to duro lodi si ara e ko le duro. Ti gbogbo wa ba so pe a o se mo, ko nii je ka kuro loju kan, lati tesiwaju. Maa gbiyanju lati rii daju pe mo petu si gbogbo won lokan, ka si pada di ara wa losusu owo, ka le fi debi ti a fe e de.

AWIKONKO: Nje o ti e leto ki awon sorosoro maa bu ara won lori redio, tabi ki won maa paroko ranse sira won, ati pe ona wo le fee gba lati dawo e duro gege bi alaga tuntun?
OMILANI: Eyi ti n sele lojo to ti pe, ka to o dele aye lawon agbaagba olorin ti maa n forin bu ara won, ti won a maa juko oro ranse sira won. awon onise tiata naa n se e. awa sorosoro naa n se e, ti m ba so pe a o kii se, iro ni mo pa, sugbon nkan ti mo ri sii ni pe ko bojumu to. O wa unprofessional gege bawon oloyinbo se n so, iyen ni pe ko ba ilana ise yi mu. O pelu awon agbekale ti mo so fawon ti so fun pe mo fee dupo alaga pe a gbodo maa se idanilekoo fun ara wa loore-koore. Awon kan wa ti won n se nkan ti ko dara, ti won o mo to je pe nipa idanilekoo, won a mo pe nkan tawon n se ko ba ilana ise yi lo. Awon ojogbon atawon akosemose a si maa wa lati wa da wa lekoo. Aare egbe yi lorileede Naijiria, Desmond Nwachukwu naa ti n gbiyan ju lati da ileewe kan sile, nibi ti won a ti maa da awon eeyan lekoo nipa igbohun safefe, ti a ba si n lo kekoo nibe lati ipinle Ogun, gbogbo awon nkan bayii a kuro nile. Ti a ba n ba ara wa ja, ko ye ka maa lo sori redio abi telifisan lati lo maa bu ara wa. Nkan ti a le se ni pe ka wa ona lati jo yanju aawo to ba wa laarin wa. Nkan tawon eeyan fe e gbo lori eto wa lo ye ka maa so, kii se oro ija.

AWIKONKO: Ki wa le fe ko je gege bi oro amoran fawon omo egbe paapaa bi e se di alaga tuntun yi?
OMILANI: Amoran mi ni pe ki won je ka se nkan to to, ka pa enu wa po soju kan, ka pawo po sibi kan, ka le jo gbe egbe FIBAN de ibi to ye. Atawon to ju mi lo, atawon ti mo ju lo, atawon taa jo je iro kan naa, ki won je ka yo oro eleyameya kuro ninu oro wa. Nkan to ja ju ni pe ka je ki ijoba ibile, ipinle atijoba apapo mo pe egbe kan wa to n je egbe FIBAN, iyen egbe sorosoro. A gbodo le fi apeere lele fawon eeyan ti a fi awon eto wa gbanimoran pe looto la wa naa je awokose. Ki won je ki omode to subu to wo iwaju, ati agba to subu to woe yin wo, ka jo tun oju ona yi se, ki won si sowopo pelu ijoba mi, ki egbe yi le goke agba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI