Leyin odun kerinla; awon eeyan si n seranti Oloogbe Yomi Ogunmola - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 13, 2017

Leyin odun kerinla; awon eeyan si n seranti Oloogbe Yomi Ogunmola

Kii se iroyin tuntun mo pe gbajumo osere tiata nni, Oloogbe Yomi Ogunmola ti papoda, sugbon nkan to si n je kawon eeyan si maa ranti e dasiko yi ni awon ipa to ti ko laarin awon egbe osere tiata lorileede yi ko too ku.

Oloogbe Yomi Ogunmola
Fun awon to ba mo okunrin oloogbe yi daadaa, yoo mo pe iru e ko pe meji nigba aye e, ko da, bawon eeyan se n kan saara si Odunlade Adekola lasiko yi, bee naa ni won n gbosuba kare fun Yomi Ogunmola nigba naa.

Lara awon fiimu tokunrin naa ti ko pa ko too ku ni “Ayo ni mo fe” se lodun 1994, sinima naa lo si tun je ki okiki won kan jake jado orileede yi, to fi mo oke okun.

Bee naa lo tun kopa to joju ninu fiimu “Ago Kan Oru” lodun 2003, ati pe Yomi Ogunmola gangan lo dari fiimu naa, eyi lo fa a tawon ololufe e, paapaa awon osere tiata to sunmo, atawon ti won jo sise po ko se le gbagbe e titi di bi a ti n koroyin yi.

Ojo Aje Monde ose to m bo, iyen ojo ketadinlogun ni yoo pe odun merinla gbako ti Oloogbe Yomi Ogunmola, to je egbon fun Peju Ogunmola file saso bora, bo tile je pe ojo keerindinlogun ni saseye ikeyin pelu ale awon osere tiata (artistes’ night) fun un nile e to wa ni Abule Egba nipinle Ekoo, iyen lodun 2003.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI