Se
loro tun di boolo o yago lojo Aje Monde ose to koja ni osibitu ijoba tipinle Ekoo,
Lagos State Teaching Hospital, LUTH nigba tawon dokita tun sawari aarun iba
LASSA lara awon eeyan meta otooto leyin ti won sayewo won.
Eyi
lo faa ti won fi ko awon eeyan to le ni aadoje (150) sabe ayewo nitori ti won
gba pe oo seese kawon naa ti lugba aarun yi, bo tile je pe se lopo won yari pe
awon n lo sile nitori pe ko si nkan to se awon sugbon tawon dokita so pe ayafi
tawon ba ri aridaju pe ara awon eeyan naa mo lawon yoo to fi won sile lati maa
lo sile.
Nigba
to n soro nibi ipade ti won se pelu awon oniroyin laipe yi, olori awon dokita nileewosan
LUTH, Ojogbon Chris Bode salaye pe looto lawon tun salabapade aisan naa lara
enikan, bo tile je pe awon ko le so pato bo tun se sele, sugbon tawon ti n se
awon nnkan to ye fun un.
No comments:
Post a Comment