Nise loro di boo lo o yago lona lojo
Abameta Satide to koja lo lohun nigba tawon oni fayawo atawon eso asobode
(custom) koju ija sira won lopopona Olorunda si Idiroko nijoba ibile Yewa South
ipinle Ogun, nibi ti won lawon eeyan ti farapa yannayanna.
Gege b'AWIKONKO se gbo, won so pe fun
bii wakati meta gbako lawon eeyan naa fi ja ija igboro naa nigba ti won so pe
awon oni fayawo ni won deede loo kolu awon osise eso asobode lakoko ti won n
sise won lowo.
Ohun ta a gbo ni pe, won ni wahala
tawon eso asobode naa n fawon eeyan lagbegbe naa ti poju, ati pe awon ti won ba
mo ni won n je ki won se fayawo raisi wole bo tile je pe pelu egunje ti won gba
lowo won ni won fi n fun won laaye.
A gbo pe owo ti won lawon eso asobode
naa tun n beere lori raisi kan ti won ba gbe ti po ju owo ti won n gba lowo
awon ti won n ba se fayawo raisi naa lo, eyi lo si je ki won pinu pe a fi kawon
ja feto awon bayii.
Lojo naa la gbo pe ojiji ni ikolu naa
je fawon osise asobode yi ti won so pe jeje won ni won n koja lo, ko too di pe
awon eeyan naa to le ni ogorun loo kolu won pelu orisirisi eroja oloro bii ada,
obe, oogun abenugongo atawon nkan min in.
Gege bi eni kan to wa lolobo se so, o
ni ere lawon osise asobode naa koko pe e sugbon nigba ti won ri owo tawon eeyan
naa gbe wa ba won, lo je ki won na papa bora, nitori taa gbo pe bi won se n
yinbon lu won ni ko wole.
Eni naa so pe nigba tawon osise asobode
yi sa asala Femi won tan ni won fi raaye lati ba moto won je, ti won fo gbogbo
gilaasi ara e, bee ni won tun jo taya mereerin to wa lese e.
AWIKONKO tun rii gbo pe asiko tawon
osise asobode sawon igbo ni won fi ranse sawon eeyan toku, ti won tun te awon
olopaa ati soja laago lati was daabo bo Emi won, sugbon ki won too de be, awon
eeyan naa ti lo.
Ni bayii ohun taa gbo ni pe owo olopaa
ti ba meta ninu awon olokada to n se fayawo yi, ti won si tun ti gba okada ti
ko din ni metadinlogun, iyen lasiko taa n sakojopo iroyin lowo.
Oga Agba fajo eso asobode nipinle Ogun,
Ogbeni Sani Madugu nigba to n soro so pe ko si nnkan meji to je kawon eeyan naa
maa binu bi ko se bawon se pase pe won ko gbado se fayawo raisi wole mo, tawon
si ti loo dina mo won lawon ona ti won maa n gbe ise fayawo won gba.
O lawon gba moto mejo, eyi ti meji ninu
e je tokunbo to je pe raisi nikan I won ko sinu won bamubamu, ati pe ibi ti won
ti n ko raisi sinu Awon moto naa lasiri won ti tu sawon lowo.
Madugu so pe awon sense bere igbogun ti
pelu awon eeyan naa ni nitori tawon ko nibi foju boro bawon se mo, ati pe eni
towo palaba e ba ti segi, ile ejo lawon yoo gbe e lo.
No comments:
Post a Comment