Eyii ni ayanfẹ mi ati egbe oṣelu APC ni Kwara - Gomina AbdulRazaq fa Abdulfatai Seriki lọwọ soke fun ipo gomina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 19, 2026

Eyii ni ayanfẹ mi ati egbe oṣelu APC ni Kwara - Gomina AbdulRazaq fa Abdulfatai Seriki lọwọ soke fun ipo gomina

Bi eto idibo abẹle fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ṣe n sunmọ etile, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fa ọwọ Ambasidọ Abdulfatai Yahaya Seriki soke gẹgẹ bi ẹni ti yoo gba ipo naa lọwọ rẹ lọdun 2027.

Laipẹ yii ni Gomina AbdulRazaq kede Abdulfatai Seriki gẹgẹ bi ọmọ oye ti yoo gbe asia ẹgbẹ ninu eto idibo to n bọ lọdun 2027.

Nigba to n sọrọ, gomina sọ pe lẹyin gbogbo oniruuru ipade pẹlu awọn agbaagba ati alẹnulọrọ kaakiri ipinlẹ Kwara, ati agbeyẹwo, awọn fẹnuko lati fa Ambasidọ Abdulfatai Yahaya Seriki kalẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.

AbdulRazaq sọ pe gẹgẹ bi ọdọmọde ti Seriki jẹ, o ti ṣiṣẹ ribiribi nipa didokoowo lagboole oṣelu kaakiri ipinlẹ Kwara.

"Nko ni iye meji nipa okun ati agbara rẹ, ati pe iru eeyan bii tiẹ lo dara fun awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ wa lasiko yii," Gomina sọ bẹẹ.

AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe fifa ọwọ Seriki soke ko di awọn oludije yooku lọwọ lati kopa ninu eto idibo abẹle to n bọ l'Ọjọbọ

"Igbesẹ yii ko ṣe idena si awọn adije yooku lati kopa ninu eto idibo abẹle, mo rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn alakoso lati buwọ lu Seriki gẹgẹ bi ọmọ oye wa fun iṣọkan ati itẹsiwaju aṣeyọri ẹgbẹ bi a ti n lọ sinu eto idibo abẹle l'Ọjọbọ, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2026."

O ni wi pe awọn yan Yahaya Seriki, iyẹn ko tunmọ si wi pe iyẹn ti ja awọn oludije to ku kuro ninu ere ije naa, ṣugbọn to ni ohun to daju ni pe ẹnikan ṣoṣo ni yoo jawe olubori si ipo kan ṣoṣo ti awọn mẹrindilogun n du.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI