Awọn ọba alaye ṣabẹwo idupẹ si Gomina AbdulRazaq lori gomina tuntun to n bọ lẹyin rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 25, 2026

Awọn ọba alaye ṣabẹwo idupẹ si Gomina AbdulRazaq lori gomina tuntun to n bọ lẹyin rẹ

Lopin ọsẹ ti kọja yii, ni gbogbo awọn ọba alaye nijọba ibilẹ Ariwa ipinlẹ Kwara ko ade ati ilẹkẹ oye wọn lọ siwaju Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati fi ẹmi imoore han.

Wọn ni iwuri nla ati idunnu alailẹgbẹ lo jẹ fun awọn pe gomina jo si ilu ti awọn lu, nipa fifa ọmọ oye fun ipo gomina kalẹ, eyi to wa lati agbegbe awọn.

Bakan naa ni wọn tun dupẹ gidigidi lọwọ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu to da si ọrọ naa, lati jẹ ki erongba wọn wa si imuṣẹ.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti wọn kede olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Ọnarebu Salihu Yakubu Danladi kalẹ gẹgẹ bi ẹni yoo gbe asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lọdun 2027.

Nigba to n gba ẹnu awọn ọba alaye naa sọrọ, Etsu tiluu Patigi, Alaaji Ibrahim Umar Bologi keji, to lewaju wọn, sọ pe oriire nla lo wọle tọ wọn lọsan gangan.

O lawọn ko le ṣai dupẹ lọwọ Aarẹ Bola Tinubu, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ati gbogbo awọn alẹnulọrọ patapata, ti wọn rio daju pe awọn ara ẹkun Ariwa Kwara fa adije sipo gomina kalẹ.

"Ọlọlajulọ, gomina wa, gbogbo awọn ọmọ ati olugbe Ariwa Kwara lo wa nibi ni ọsan oni lati dupẹ fun ohun ti ẹ ṣe fun wa. Ọkan lara awọn ọmọ wa, Ọnarebu Salihu Yakubu Danladi, lo jẹ ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo gomina ninu eto idibo ọdun 2027, ti a si dupẹ gjidigidi," Etsu Patigi, Alaaji Ibrahim Umar Bologi keji sọ bẹẹ lasiko abẹwo si gomina niluu Ilorin.

"A wa nibi lọsan yii lati sọ pe ẹ ṣeun lọpọlọpọ, ki Allah tubọ maa dari yin, ko si maa pa yin mọ," o fi kun ọrọ rẹ.

Bakan naa ni ọba alaye yii tun fi ẹmi imoore han si awọn iṣẹ akanṣe ti gomina ṣe fun wọn lẹkun Ariwa ipinlẹ Kwara, paapaa awọn iṣẹ idagbasoke.

Nigba toun naa n sọrọ, Gomina jẹ ko di mimọ pe abẹwo naa lo fidi iṣọkan wọn mulẹ nipa ibi ti wọn pin ipo gomina si.

AbdulRazaq sọ pe bi adije ṣe jade lati ẹkun Ariwa Kwara fidi rẹ mulẹ nipa yiyi ipo naa, lai si ojusaaju nimu eto idari nipinlẹ naa.

"Gbigbe ipo oṣelu kaakiri ṣe pataki fun aisi ojusaaju. Eyi tun dara fun idagbasoke ati jijẹ ki awọn eeyan nipin ninu eto iṣejọba. Idi ree to fi jẹ pe ni apapọ, ipo aarẹ n lọ kaakiri ẹkun Ariwa ati Guusu.

"Eyi n ṣẹlẹ nitori idagbasoke, alaagia, iṣọkan ati aisi ojusaaju. Ohun ti a si n foju sọna fun nibi naa niyẹn," gomina sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI