E fura o, awon omo kekeeke ti n segbe okunkun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 8, 2017

E fura o, awon omo kekeeke ti n segbe okunkun

Nise ni enu ya opo awon eeyan lojo Monde to koja nigba tileese olopaa ipinle Ogun safihan awon omo kekeeke metala tojo ori won ko ju odun mokandinlogun lo, ti won n se egbe okunkun labule Mosunmore, Kobape niluu Abeokuta. 

Ko si nkan meji to je koro naa se awon eeyan ni kayeefi bi ko se tawon omodebinrin merin tojo ori won ko ju mewaa si metala lo, ti won lawon naa sese darapo mo egbe okunkun ti won pe ni Penalty Guys yi ni. 

Won lawon omo yi sese pari ileewe alakobere, pamari siisi ni, ti won n foju sona lati wo ileewe girama lonii ojo Monde. 

AWIKONKO gbo pe o tu asiri won sita ni bi iya okan lara awon omo yi se loo foro naa to awon Baale won leti awon omo kan labule ti mi omo oun wonu egbe buruku yi, ti won si gba tesan olopaa lo wa ni Owode-Egba lo lati fejo sun. 

Iya omo naa lo sakiyesi omo e nigba to yo kelekele jade ni nnkan bi aago mesan aabo, to si pe ko too wole pada, ero okan e tele ni pe boya odo awon to fe maa ba a sun lo ti n bo. 

Latigba naa lo so pe iwa e ti yi pada, sugbon nigba to di nkan bi aago meta osan lo beere lowo pe nibo lo lo lale and, iyen lojo Sande, ojo ketadinlogun, to si ko lati so o. 

Igba to bere sii lu lati mo ibi to lo, lo jewo pe awon omo kan ladugbo lo n dun koko moun pe boun ko baa darapo mo egbe okunkun won, won yoo pa oun danu, eyi lo faa toun fi loo ba won. 

Ara abiyamo to ta obinrin yi lo fi gba ile Baale won lo ni nnkan bi aago mefa aabo irole pe ko tete wa nnkan se soro awon omo to fee baye omo oun je, nitori ti won loo so pe oun ko fee foju sunkun omo. 

A gbo pe esekese tawon olopaa ti gbo ni won ti yan awon otelemuye lati loo sewadi, sugbon siyalenu, nigba ti won maa ri won mu, ibi ti won tun ti n sebura fawon omo min in ni won wa, to won fi ko gbogbo won loo tesan. 

Nigba tawon omo naa n soro logba Eleweran, eni to je olori won, Tunde Adio, omodun mokandinlogun so pe ore oun kan lo mu oun wonu egbe okunkun naa ninu osu kinni odun yi. 

Adio ni lakoko ayeye Easter tawon lo so soosi eni to je igbaketa oun, Raphael Adewale, omodun metala,  loun pinu lati da egbe okunkun toun sile, toun si fun loruko Penalty Guys.

O tun so pe igbakeji oun, Sunday Silas, omodun meedogun lo mu aba wa pe kawon se aso, aso tawon se lo je ki egbe naa wu awon omobinrin to wa ladugbo ti won si gba lati darapo mo awon.

No tile je pe Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti tare won sodo awon olopaa to n ri soro ajinigbe ategbe okunkun, SCIID lati tubo sewadi siwaju sii, sibe ko tii le ka mo igbese boya won yoo gbe won lo sileejo tabi ki won fiya je won. 

O wa gbawon obi atalagbato lamoran pe iranlowo won lati maa tawon olopaa lolobo lo le je kise olopaa yo, bee lo ni won ko gbodo fun paara lori iwa ati ise awon omo won. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI