Udoh to fipa ja ibale omo kekeeke meta n'Ijoko ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 8, 2017

Udoh to fipa ja ibale omo kekeeke meta n'Ijoko ti ha o

Kayeefi loro baba agba radarada alainitiju eni odun metalelogoji, Ini Udoh ti won loo fipa ja ibale awon omo kekeeke meta tojo ori won ko tii ju odun mejila lo. 

Ojule keji, adugbo Agboola ni Ijoko ijoba ibile Ado-Odo Ota, ipinle Ogun ni won so pe Udoh n gbe pelu awon obi awon omo meteeta naa, bo tile je pe a foruko bo awon omo naa lasiri, sugbon eyi to dagba ju ninu won ni odun mejila nigba tawon meji toku je omodun mesan an. 

Gege b'AWIKONKO se gbo, won loo ti pe ti okunrin yi ti maa n ko ibasun fawon omo naa daadaa, atipe nise lo tun maa n hale mo won pe oun yoo foju won ri mabo, ti won ba fi le soro naa sita. 

Iyalenu lo je pe ko si eyi ninu awon omo meteeta naa to mo pe awon jo n gba kinni ponla abe baba osi naa, nitori taa gbo pe asiko otooto lo maa n se kini ohun fun won. 

Won ni asiko ti awon obi awon omo yi ko ba si nile lokunrin naa maa pe won wonu yara e, pe oun fee ran won nise lai mo pe ohun to maa se ti wa lokan e. 

Gbara ti eyikeyi ninu awon omo to balance yi ba ti wole too, la gbo pe o ti maa sare tilekun leyin, ki enikeni maa baa wole ri won lasiko ti idan ba n lo lowo. 

Nigba ti asiri maa tu lose to koja, okan lara awon omo yi to je omodun mesan an ni won so pe iya e n ba fo aso, nigba to si n fo pata e lo sakiyesi kinni kan to dabi kelebe ninu pata omo e yi, eyi lo faa ti won lobinrin naa fi sayewo e daadaa, to fi rii pe ato okunrin (sperm) ni. 

AWIKONKO gbo pe obinrin naa ko fi para rara, lo ba sare pe omo e, lati beere awon oro orisirisi lowo, to si jewoo fun un pe Udoh lo maa n gbe kinni nla abe e soun labe, to si maa n dunkoko pe oun ko gbodo soo sita fenikan kan. 

"Mo ku, mo gbe, mo daran" lariwo tobinrin naa pa pe kawon ara adugbo gba oun lowo Udoh nitori to ti baye omo oun je, toro naa si dariwo. 

Ibi ti won ni won ti n fa oro naa lawon omo meji toku naa tun ti soro jade sita pe kii se omo yen nikan lo n ba sun, o tun maa n se kinni naa fawon. Igba yi gan ni won loro naa tun di isu ata yanyan. 

Lesekese lawon araadugbo ti pe le Udoh lori, ti won bere sii gbe e sepe rabande-rabande nitori bo se fee baye awon omolomo je lati kekere. 

Lara awon araadugbo naa ti so pe ki won loo foro naa to awon olopaa leti, ko too di pe awon baba awon omo meteeta gba yi , Ogbeni Lateef Sikiru, Ogbeni Lawrence Effiom ati Ogbeni Ikechukwu Udozor fi gba tesan olopaa to wa ni Sango lo lati loo fejo sun nibe. 

AWIKONKO rii gbo pe awon olopaa ni won ni ki won ko awon naa lo si osibitu lati loo sayewo, kawon le loo gege bi eri tawon yoo fi gbe Udoh lo sileejo. 

Ni bayii, Komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu ti pase pe kawon eka olopaa to ri si lilo omo nilokulo ati fifomo seru, lati tesiwaju ninu ejo naa. 

O wa gbawon araalu paapaa awon obi lamoran pe ki won rii daju pe won n mojuto awon omo won daadaa paapaa lasiko taa wa yi bo se je pe awon eeyan n wa orisirisi ona lati se omolomo nisekuse. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI