Won gbe soosi Ridiimu lo sile ejo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 28, 2017

Won gbe soosi Ridiimu lo sile ejo

Opo awon eeyan ni won la enu won sile ti won ko le pa a de ni ileejo giga to wa ni Isabo niluu Abeokuta, ipinle Ogun lojo Aje Monde ose to koja nigba ti won rii bi molebi kan se wo soosi Ridiimu, Redeemed Christian Church of God lo sile ejo lati loo kawo poyin rojo.

Ko si nkan mejo to mu ki molebi naa, iyen molebi Odi gbe soosi Ridiimu naa lo sile ejo, bi ko se ti oro ile (land) ti won so pe won ra lona aito, eyi ti won so pe okunrin kan ti ko fibi kankan tan mo molebi won, Dominic Odi feru ta fun won.

Gege b'AWIKONKO se gbo, ileese DOVE QUARRY to je eka to n pawo wole fun Ridiimu ni won fesun naa kan niwaju Onidajo M.O Dipeolu pe won ko ri enikankan ninu molebi won ki won too ra ile lowo Dominic tawon ko mo ri.

A gbo pe ileese kan, TRUST OF D1 QUARRY lawon ebi gbe ile won fun pe ki won maa se abojuto e, ki won si maa se ise won nibe, titi digba tawon yoo fi pinu lati ta a.

Won ni se ni Dominic loo ji ninu ile naa ta fun ileese kan, ti won si fee le awon ti molebi ti fi sori ile naa kuro ni tipatipa. Bee ni won tun so pe won n dunkoko mo won pe ki won kuro ni tipatipa.

AWIKONKO gbo pe ileese Dove Quarry naa ti was pe ejo ti nomba e je AB/280/2017 lati fii tako awon to n ja sile naa pe kileejo da won lowo ko lati ma se yo won lenu titi digba ti won yoo fi pari ejo naa laarin ara won.


Nigba to n sedajo e, Onidajo M.O Dipeolu ti waa pase pe kawon ebi Odi si loo se suuru digba toun yoo fi yanju oro naa, ki won si fi awon to wa lori ile naa sile lati maa ba ise won lo lai di won lowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI