“E gba wa
lowo babaloja wa, wahala e ti poju” loro ebe to n tenu awon ara oja Kila nijoba
idagbasoke Orile Ilugun ipinle Ogun n fi ranse sijoba nibi ayeye ti won ti si
iso awon oni gaari fun won lojo Tosde ose to koja.
Gege b’AWIKONKO
se gbo, won ni babaloja naa, Oloye Dele Idowu la gbo pe o ti gbe gbogbo ojo ti
won ba n na oja naa lo ma n lo yo awon oloja ti won ba taja lenu, to si ma maa
gba oja lori won gege bi isakole, sugbon ti won ni ko tun n fi won lokan bale.
A gbo pe
gbogbo akitiyan lati ri owo iwa ibaje Oloye Dele Idowu bole lo n ja si pabo, ti
won loo tun gbe alaga ijoba idagbasoke, Arabinrin Mofoluke Aina Soremekun lo sile
ejo to wa nilu Abeokuta pe ko seni to lase lori oja naa, a foun.
Lojo Tosde
to koja yi lawon ara oja naa tun lo anfaani ayeye sisi iso gaari ti Onarebu to
n soju ekun Obafemi Owode, Abeokuta North ati Odeda Federal Constituency nile
igbimo asofin agba nilu Abuja, iyen Onarebu Mukaila Olayiwola Kazzim ko fun won
gege bi awon ileri to ti se.
Alaga egbe
oni gaari, Alaaji Tajudeen Lamidi topo mon on si Agbelere nigba to n b’AWIKONKO
soro pelu ibanuje okan so pe gbogbo akitiyan lawon ti sa lati da babaloja ati
iyaloja, Arabinrin Adunola James naa lowo ko sugbon to ja si pabo.
Bee naa ni
igbakeji alaga egbe oni gaari, Arabinrin Folake Jinadu so pe yato si tikeeti
oja tawon n ja, babaloja naa tun n gba isakole lowo won, to si je pe gbogbo ere
to ye kawon je lori oja won lawon fi n san isakole.
Nigba toun
naa n soro, Arabinrin Mofoluke Soremekun, alaga ijoba idagbasoke Orile Ilugun
so pe isoro tawon ni ninu oja naa ko pe meji, bi ko se ti wahala ti babaloja
naa n fawon ara oja yi lo.
Lati gbo
tenu babaloja ati iyaloja naa, awon mejeeji so pe ko si nkan tawon fee so
nitori pe se ni won lo anfaani sisi iso gaari lati wa fi yeye awon lojo naa, bo
tile je pe awon ko fee yoju tele, sugbon tawon kan be awon pe kawon wa.
Ohun taa
gbo ni pe babaloja, iyaloja atawon kan ti pinu lati ma yoju sibi ayeye naa,
sugbon ironu wipe won maa ri owo gba lowo Onarebu Mikky Kazeem lojo naa lo gbe
won wa, gbogbo bi won si se wa nibi ayeye ni inu won ko dun pelu bawon eeyan se
foju tembelu won.
No comments:
Post a Comment