Eyi ni bi Gomina Ambode se di alaga egbe awon Gomina leyin odun mejila - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 24, 2017

Eyi ni bi Gomina Ambode se di alaga egbe awon Gomina leyin odun mejila

Titi di asiko ti e n ka iroyin yi lawon eeyan to nife Gomina ipinle Eko, Akinwunmi Ambode fun ise ribiribi manigbagbe to n se nipinle naa lo si n ki ku oriire ti ipo tuntun ti won sese yan an si lojo Aje Monde to koja yii.

Gomina Amosun, Gomina Ambode ati Gomina Akeredolu
Gege b'AWIKONKO se gbo, won yan Gomina Ambode gege bi alaga egbe awon gomina Southern ninu atejade ti won fi sita leyin ifikunlukun ti won se nibi ipade awon Gomina to waye ni Ikeja, ipinle Eko.

Be o ba gbagbe, odun 2005 ni won ti se iru ipade yi keyin nipinle Eko, bo tile je pe ipinle naa ni won ti koko bere e lodun 2001, sugbon lati odun 2005 naa, eyi to waye yii lo maa je eleeketa tiru e maa tun pada waye nipinle Eko.

Bakan naa ni won tun yan Gomina ipinle Bayelsa, Seriake Dickson ati Gomina ipinle Ebonyi, David Umahi gege bi amugbalegbe Gomina Ambode.

Nje e ti gbo: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/pasito-jeremiah-atawon-merin-to-n.html 

Ninu ipade naa ni awon gomina metadinlogun to wa ni ekun Southern lorileeede yii ti fenuko wi pe atunto nikan lo le mu ilosiwaju ati idagbasoke ba Naijiria.

AWIKONKO gbo pe, bo tile je pe won ko tii fenuko nipa ojo ti ipade miran yoo waye, sugbon ta a gbo wi pe ilu Port Harcourt nipinle Rivers ni won ti maa se.

Lara awon Gomina to tun wa nibi ipade naa ni Gomina Ayodele Fayose tipinle Ekiti; Gomina Rauf Aregbesola tipinle Osun; Gomina Rotimi Akeredolu tipinle Ondo; Gomina Abiola Ajimobi tipinle Oyo ati Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun.

Nje e ti gbo: https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/ogd-fee-pa-egbe-oselu-pdp-ni-o-kasamu.html 

Awon min in tun ni Gomina Nyesom Wike tipinle Rivers; Gomina Godwin Obaseki tipinle Edo; Gomina Okezie Ikpeazu tipinle Abia; Gomina Ifeanyi Ugwuanyi tipinle Enugu; Gomina Emmanuel Udom tipinle Akwa Ibom ati Gomina ipinle Ebonyi, David Umahi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI