Eyi ni bi iji se ba ileewe FCE je l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 12, 2017

Eyi ni bi iji se ba ileewe FCE je l'Abeokuta

Bo tile je pe orin ko si owo nile lorin tawon oga agba ileewe awon olukoni niluu Abeokuta, iyen Federal College of Education, Abeokuta n ko, ti won si n rawo ebe sijoba apapo lorileeede Naijiria lati tete boju aanu wo won latari bi iji nla kan se ba opo awon ile je ninu igba ileewe naa lojo Isegun Tusde to koja yii.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni deede aago meji aabo osan, ati pe lasiko tawon akekoo leka ikekoo bii meloo kan ko tii pari idanwo fun saa ikekoo yii n se idanwo lowo ni ojo naa bere, to si bere pelu iji lile ti ko seni to mo pe iji naa maa koja oju tawon fi wo o.

Ohun taa gbo ni pe ere lawon eeyan naa koko pe e nigba ti iji nla naa bere, nitori ta a gbo pe se ni won ro pe iji naa ko le yato sawon iji to ti n ja lateyin wa lo, ti won ko mo pe iji naa maa ba opolopo nnkan je.

Lara awon ibi ti iji naa baje ni ileese oga agba ileewe naa, iyen Provost; gbongan nla ti won loun lo tobi ju, iyen gbongan Maina nibi ti won lawon akekoo ti n se idanwo lowo; ofiisi Dean; laabu ti won ti n dawon akekoo lekoo, iyen  Micro Teaching Laboratory ti won so pe opolopo ero komputa lo kun ibe; ileese egbe awon akekoo, iyen Students Union Government building; Gbongan idaraya ti Tunde Fulani; ileegbe awon akekoo, iyen Hostel atawon min in.

https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/eyi-ni-bi-iji-se-wo-ileewe-fce-labeokuta.html 

A gbo pe nigba ti iji naa bere sii ka paanu danu lori awon gbongan atawon awon ofiisi kaakiri, Nise lawon eeyan bere sii sa asala fun emi ara won, toro naa di boolo o yago lona.

Komureedi Bankole
Nigba to n soro, Aare egbe awon akekoo nileewe FCE, Komureedi Bankole Sodiq Ayinla so pe gbongan kan ni CEDEP loun wa lasiko naa toun loo wo ore oun kan nigba ti iji nla naa bere, to si di pe onikaluku bere sii pe awon oruko ti won gbojule bii Jesu, Anobi atawon oni tibile.

O so pe Iyalenu loro iji naa je foun nitori toun ko tii ri iru isele bee ri latigba toun ti wa ninu igba ileewe naa, ati pe bo tile je pe oun kan n feti gbo o pe iru nnkan bee n sele kaakiri, sugbon to je pe akoko iru e ni yii ninu igba naa.

Bankole je ko di mimo pe bo tile je pe ileewe ti pari idanwo gege bi won se la a sile, sugbon tawon eka ikekoo kan ko tii pari idanwo ti won, asiko naa ni iji naa ka won mo, ati pe ko tii ju bii iseju meedogun kawon to n se idanwo lowo se tan ni ojo naa bere peluu iji lile.

O lesekese lawon akegbe oun ti n pe oun lori foonu wi pe iji ti ba paanu ileese awon je, ti omi si ti wo gbogbo inu ofiisi to wa nibe, ati pe nise ni gbogbo inu ofiisi dabi adagun odo, eyi lo fa a toun naa fi gbera nigba ti iji naa dawo duro die lati loo foju ara oun to o.

Ninu oro e, o so pe "Ni deede aago meji aabo osan ni iji naa bere lakoko tawon akekoo kan n se idanwo won lowo, bo tile je pe ileewe ti pari idanwo gege bi alakale.

Bankole lakoko to n safiahn f'Awikonko
"Opolopo ile ni iji naa baje eyi ti ileese wa naa ko gbeyin. A ti n lo ile ati aso inule lati maa fi nu omi to ba wole, nigba ti ojo ba n ro nitori pe gbogbo ofiisi to wa ninu ileese wa yi ni omi maa n kun. 

"Orule awon ileegbe wa naa baje debi wi pe o fo tanka ike ti a fi n gbe omi like, iyen GeePee. O ba orule gbongan to tobi ju nileewe yi, iyen Maina to gba eeyan to to egberun kan aabo. Ofiisi Dean leka ikekoo ise owo, iyen Vocational; gbongan Kunle Filani; awon igi ti won gbin soju ona ko gbeyin ninu awon nnkan to baje, to fi mo ileese oga agba ileewe wa, iyen Provost.

Nigba to n soro lori bo se je pe awon gbongan ati ile tuntun lo po ju ninu awon ti iji nla naa sose fun, o so pe kii se pe bo ya awon agbase se ti won gbe awon ise ile kiko fun ni won ko sise daadaa, sugbon nnkan ti a ba ti ko sile ko le sai ma sele, ko si seni to le da ise Olorun duro.

Ofiisi Dean ti omi wo
Fun apeere, Bankole so pe odun 2012 ni won pari gbongan Maina, ti ko si si nnkan to se e latigba naa, ati pe opo ojo ati iji lo ti ja, ti ko si nnkan to sele sii, sugbon eleyi kan waye bi a se ko o bii.

https://iroyinawikonko.blogspot.com.ng/2017/10/ori-ko-oga-agba-fce-abeokuta-yo-ninu.html

O wa rawo ebe sijoba apapo lati tete da si oro naa lati ba won satunse lawon ibi ti iji naa baje, nitori pe ise naa ko se e da se lai ni atileyin ijoba ninu. O so pe bo tile je pe akoko olude lawon seese wa, sibe ijamba naa yo o mu ifaseyin ba ise ati opolopo nnkan ti saa ikekoo min in ba bere losu kokanla to m bo yii.

Bee lo ro awon akekoo pe ki won loo fokan won bale nitori pe igbese atunse ti n lo lowo, toun si nigbagbo pe lai pe, ijoba yii ba won da si oro naa.

Akowe owo fegbe awon akekoo, iyen Financial Secretary, Komureedi Salako Olawale Ayomipo so pe inu ofiisi loun wa nigba ti iji naa bere, ti aya onikaluku si bere sii ja bi eni pe opin aye ti de.

Salako so pe nigba ti ojo naa rawo duro die, lawon jade sita lati maa lo kaakiri lo wo awon ibi ti iji naa to sose, tawon si rii pe opolopo nnkan ni iji nla naa baje, to fi mo oja tawon akekoo ti maa n sise, ati ibi ti won ti n ra nkan.

O lopolopo dukia ni iji naa baje koja afenuso, ati pe awon alase ti wa a bawon soro lati fokan bale pe ise atunse maa bere lai pe, kawon si lo o ko nnkan toju awon ri lakoko ati leyin isele naa.

Okan lara awon akekoo to so pe oun wa lara awon akekoo to n se idanwo lowo, Kehinde Abosede so pe awon ko tii pari idanwo nigba tisele naa sele, o ni foonu toun toju segbe kan loun too wonu gbongan lati se idanwo lojo naa, omi wonu e to je pe Olorun lo ba oun se e ti ko baje.

Bettermore
Komureedi Ganiyu Moruf tawon eeyan tun n pe ni Bettermore, to je okan lara Awon oluyaworan ninu ogba ileewe naa, nigba to n b'AWIKONKO soro so pe iyalenu loro iji naa je foun, ati pe nise nisele naa dabii pe won ran iji naa sinu ogba ni.

O ni ile oni paanu ti won fi irin gbe duro sori awon soobu bii meloo kan ni iji nla naa gbe daju, to si juu mole leemeeta otooto, ati pe die lo ku ki eni kan ti kini naa kolu farapa yan-na-yan-na, bo tile je pe o fara gbogbe die.

Bettermore so pe inu moto loun ati onibara oun kan wa, sugbon toun so fun eni naa pe ko je kawon sun kuro labe igi nitori pe o lewu Keegan duro labe igi ti ojo ba n ro, O ni afi bi eni pe emi n ba oun soro ni, nitori pe ko ju iseju kan lo tawon sun moto naa siwaju ni igi tawon duro labe e suburb lule.

Okunrin naa so pe okan lara awon oluko lekaa ikekoo ise orin (Music Department) to paaki moto e save igi, iji naa gbe ile wo moto e mole. O dupe lowo Olorun pe bo tile je pe dukia lo baje, sibe ko gba emi lo.

Bee loun naa ro awon alase ati ijoba pe ki won boju aanu wo awon nitori pe iji naa ba soobu tawon ti n ri owo ounje je koja afenuso.

Eunice
Okan lara awon akekoo to loun n mura idanwo lowo lojo naa, Eunice Oriyomi to m foju sona fun ipele keta (300level), so pe idanwo Chemistry loun gbaradi lowo nibi toun wa lakoko isele naa.

O loun koko ro pe opin aye ti de ni nitori toun bere sii korin, toun tun bere sii pariwo oruko Jesu, sugbon nigba to ya, gbogbo e dawo duro, toun si dupe lowo Olorun.

Igbakeji oga agba, to tun je adele, nigba to n b'AWIKONKO soro nipa ijamba naa, Dokita Rafiu Soyele so pe lojiji ni isele naa ba won, nitori pe awon ko mura sile fun in, ati pe akoko re e ti iru nkan bee maa sele.

O banuje pe asiko ti ko sowo nile lati naa niru ijamba yi waye, to si rawo ebe sijoba apapo lati ran won lowo, lati satunse awon ibi ti ojo naa baje.

Soyele so pe a fi kijoba apapo tete da si oro naa, ki won si sagbateru bi awon atunse to ye se maa waye ko too di pe awon akekoo wole saa tuntun losu kokanla to m bo yi.

Bee lo dupe lowo Olorun pe ijamba naa gba emi enikeni lakoko to sele nitori pe to ba je pe awon eeyan fara pa ju bo se ye, o seese ko je pe nnkan tawon n so yi ko ni won o ba maa so.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI