Gomina Amosun fe e ran awon eeyan lo sewon - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 20, 2017

Gomina Amosun fe e ran awon eeyan lo sewon

Beeyan ba gbo bi Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun se n soro lojo Eti Fraide ose to koja yi, yoo mo pe ko mu oro naa ni seresere rara nitori to ti pinu lati bawon to n gbe iroyin buruku nipa e wo iya ija.

Nibi ipade Town Hall ti ileese to n soro ise, iyen Ministry of Budget and Planning ipinle Ogun sagbekale e lati fi so awon ise tijoba fe e se lodun to n bo, iyen 2018, to waye ninu gbongan asa, Cultural Centre, Kuto Abeokuta ni Gomina Amosun ti fibinu so iyalaya oro, to si leri pe a fi koun ran awon eeyan lewon.

Idi ti Gomina Amosun se leri yi ko seyin iroyin kan ti won n gbe kaakiri ori ero ayelujara lose meji seyin pe ajo to n gbogun ti sise owo ilu mokumoku, iyen EFCC se loo ye ile e to wa ni Ikeja ipinle Ekoo wo lati mo boya o gbe owo pamo, eyi ti Ajo EFCC tako iroyin naa lesekese pe ko ri be.

Ninu oro Gomina Amosun lakoko naa lo ti so pe “Ni bii ojo mewaa seyin, emi o ti e mo nkankan, iyawo lo je ki n tete mo, ti enikan tun beere lowo mi pe a se mo ni owo to to yi, mi o si je koun naa wa je nibe, mo so fun un pe nibi lowo naa wa, o so pe won tun ti ko nnkan ti won maa n ko.

“Mo ni ko ma dawon loun nitori pe awon kan ni loo jokoo si koro yara won lati maa ko ikokuko naa. Eni ti ori e pe to loun fe e se Gomina ipinle kan, kaka ko jokoo lati maa ronu nipa awon nkan to fe e se lati fi mu idagbasoke ba ilu e, a a wa lo wa awon oponu kan ti won ko ni anfaani kan ti won fe e se labe bo ti le wu ko ri lati maa ba awon kan loruko je nipa kiko ikokuko sita.

“Ko seni to le ba Amosun loruko je tabi ki won da ijoba e ru o, mi o ti e ri awon nkan ti won n ko, nitori pe ko kan mi rara. Won a kan maa ko orisirisi ikokuko. E je ki n fi da yin loju, awon eleyi, won n lo sewon o, mo fi n da yin loju. (We are going to smoke them to serve as deterrent, they will go to jail).

“Ewon ni won n lo, nitori naa ki eyin baba wa Kabiyesi ma wa lati be mi rara nitori pe iru e ti sele ri. Mi o fe gbo wi pe boya asise ni, won gbodo lo sewon ni, nitori pe won ye lati lo sewon.

“Bi eeyan ba ji, o ye ko ronu awon nkan to fe e se fun ipinle Ogun lori bo se ma a dagbasoke, kii se pe ko wa lo o ko awon kan ti won ko nise tabi ironu, ti won a loo jokoo sibi kan lati maa gbe opolo lati ba n kan je kale.

“Idi ni yii ti mo maa so fawon ti ori won pe, ti won n pe mi lati beere oro lowo mi pe ki won ma da won lohun, ki won seni eni ti ko ri nkankan. Gbogbo won ni mo mo, ti mo si le daruko won.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI