Won pa Bantefa nipakupa ni Sagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 16, 2017

Won pa Bantefa nipakupa ni Sagamu

Bo tile je pe awon olopaa si n se iwadii labele lowo, sibe iyalenu nisele buruku naa si n je fawon fawon ara agbegbe Isale Oko niluu Sagamu, ipinle Ogun lori bi awon adigunjale se pa baba agbalagba eni odun mejidinlaadorun (68), Bantefa Oyebanjo

Gege b'AWIKONKO se gbo, oru ojo Satide mojumo Sande ni won so pe awon adigunjale loo sileepo Oando ti Isale Oko naa, nibe ni won so pe Oyebanjo ti ba won woya ija ko too di pe omi teyin wogbin lenu, ti won si se oloogbe naa nisekuse.

Adugbo Itunla Quarters legbe Aafin Akarigbo tile Remo ni won so pe baba agbalagba oloogbe naa n gbe pelu awon omo e atawon omo omo e, ti won lo ti doloogbe, iyen Toyin.

Bo tile je pe orisirisi aheso la gbo pe o fa a tawon adigunjale naa fi loo sile epo naa, sugbon lara ohun taa gbo ni pe owo kan ti won so pe awon osise ileepo naa pa lojo Satide ojo keje osu yi to le ni milionu meji lo han sawon adigunjale naa, ti won fe e lo gbe.

Won ni se lawon adigunjale naa tun gbe ero amunawa jenereto ati irinse ti won fi n ge irin wa sibe loru ojo naa lati fi ge ilekun irin to wonu ofiisi ileepo naa.

AWIKONKO gbo pe ibi ti Oyebanjo won loo ti le lodun marun in to ti n sise sikioriti nileepo Oando naa lugo si lawon adigunjale naa ti won lawon olopaa si n wa won wa, to ti n gburo pe awon kan n yo kelekele layika ileepo naa, to si seese ko je pe ise ibi ni won fee wa se nibe.

Lesekese ni won loo ti dide lati loo loju won, toro naa si di isu ata yan-an-yan laarin won, ko too di pe won bere sii lu lalubami, ati pe nigba ti won so pe agbara awon jagufa naa ko fee ka Oyebanjo je ki won pinu lati de lowo atese.

A gbo pe gbogbo bi won se n fi ada sa Oyebanjo lara ni ko wole, eyi lo fa a ti won fi so pe afi kawon rii daju pe awon gba emi e, ko too di pe won sa a, ti won si gun un pa.


Ohun taa gbo ni pe okan lara awon osise ileepo naa lo ri Oyebanjo nibi ti won pa a si, ti won tun fi paali atawon aso kan bo o mo, to si ke gbajare sawon araadugbo pe ki won gba oun.

Lesekese ni won lawon ero ti pe jo lati loo wo nnkan to n sele, ko too di pe won ranse sawon olopaa, ti won si gboku naa lo si mosuari OSUTH to wa leyin aafin Akarigbo tile Remo.

Michael, aburo Bantefa
A gbo pe awon olopaa tun ko awon osise ileepo naa to fi mo manija lo si tesan won, sugbon osan ojo naa ni won gbe won lo si oliulese olopaa to wa ni Eleweran Abeokuta leyin tiroyin naa kan si Komisana lati tubo foro wa won lenu wo.

Okan lara awon ore Oyebanjo to ko lati daruko e so pe iku oro ni won fi pa oloogbe naa, ati pe aini ibon lowo lo fun won laye je nitori pe oun mo ore toun ni, ko nii gba fun won.

O so pe bo tile je pe Bantefa ko nigbagbo ninu oogun ibile, eyi to fa ki ko fi ni onde tabi gbekude ati gbetugbetu lara lo fa a ti won fi tete muu bale, nitori pe oju lasan ko see sise ode, iyen sikioriti.

Lara awon araadugbo Isale Oko ti won n sise nitosi ileepo naa, ti won ni ka foruko bo awon lasiri to b'AWIKONKO soro so pe o seese ko je pe lara awon osise ileepo naa lo fawon adigunjale naa lowo pe owo wa nile tawon ko gbe lo si banki, ki won waa lo o gbe e.

Won ni biku ile ko ba pani, tode o le pani lo mu kawon adigunjale naa gbe irinse  dani lati fi ja ilekun ofiisi ileepo naa, ti won tun so bi won se le mu Bantefa to je sikioriti won bale lati gbemi e.

Sande Sonuiki, ore oloogbe naa so pe odo oun ni Oyebanjo wa ko too di pe o lo sibise lale Satide toun ko si fura pe ale ojo naa lawon yoo rira mo.
Cecilia, egbon Bantefa
O so pe nigba ti won pe awon tawon de be, oku e lawon ba nile, tawon tun ri bi won se ge ilekun ileepo naa. O ni okan lara awon osise ileepo naa to koko de laaro ojo naa lo pariwo sita.

Nigba to n soro, Ogbeni Michael Adeniyi Bantefa to loun ni won bi tele oloogbe naa to niluu Eko loun n gbe so pe ona soosi loun wa ki won too pe oun pe won ti pa egbon oun, lesekese loun ti wo moto lati loo wo nnkan to n sele.

Michael so pe bo tile je pe awon olopaa ti bere ise iwadii, sibe awon ti loo si kootu lati loo se afidafit pe awon ko ba ileepo naa sejo, ki won si je kawon loo si iku egbon oun ko ba maa rare ninu mosuari to wa.

O lawon fee yanju oro naa labele ko ma di pe awon ma maa tun lo maa kawon poyin ni kootu tabi lodo awon olopaa lose ose, kawon olopaa se nnkan to ba ye ki won se.

Iya agbalagba to.loun ni won bi ki won too bi oloogbe naa, Cecilia Oduwole nigba to n fomije soro so pe ibanuje NLA ninu aburo oun je nigba ti won mu iroyin naa wa foun.

A gbo pe AJC World nipinle Eko, iyen ileese to n se ipara pomade ni oloogbe naa ti sise, leyin to kuro nibe lo wa si Robber Plantation to wa niluu Sagamu nibi to ti feyin ti. Nitori ko ma baa maa jokoo lasan lo fa a to fi loo gba ise sikioriti.

Ohun ta a gbo ni pe ojo Wesde ni won sinku baba naa nilana igbagbo leyin ti won so pe won ti yanju oro naa laarin ileepo Oando atawon ebi.

Won ni egberun mejila naira ni won n so fun baba naa, ati pe won seese bere sii San owo naa fun un nigba ti eto oro aje orileede yi lo soke.

Agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe looto loun ti gbo nipa isele naa, iwadii si ti n lo labele, toun si nigbagbo pe lai pe owo yoo te awon odaran naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI