Aanu Olorun lori mi ko kere - Solanke Amebo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 8, 2017

Aanu Olorun lori mi ko kere - Solanke Amebo

Okan lara awon gbajumo oniroyin lorileeede Naijiria, Solanke Ayomideji Taiwo to tun je oludasile iwe iroyin ori ero ayelujara, Amebo Feeds Naija ti so pe aanu Olorun lori oun ko kere latari ibi toun de lonii.

Solanke ninu oro to fi ranse s'AWIKONKO laaro onii, ojo kejo osu kokanla, o so pe ko seni meji toun tun le maa dupe fun bi ko se Eleda to da emi oun si titi dasiko yii, to si gbe oun de ipele toun wa bayii.

O ni opolopo igba loun ti beere fun okun, ti Olorun si fi ta oun lore lekunrere. O loun beere fun imo, sugbon ti Olorun tun foun pelu oye lati bori isoro.

Bakan naa ni okan lara awon gbajumo osere tiata lorileeede yii, eni to tun ti pelu awon oloselu bayii, Ogbeni Rotimi Makinde naa tun ki ku ayeye ojo ibi.

Opo awon ololufe gbajumo oniroyin naa, iyen Solanke lo ti bere sii fi atejise ranse sii lorisirisi lati baa yo ayo ayeye ojo ibi e, lara won naa ni olootu iroyin AWIKONKO naa wa.

Igba Odun, iseju aaya kan ni o, fun Ogbeni Solanke Ayomodeji Taiwo, Amebo Feeds Naija (https://amebo9jafeed.blogspot.com.ng/)

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI