E wo bi omo eleran se fo VIO lori l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 13, 2017

E wo bi omo eleran se fo VIO lori l'Abeokuta

Nise loro di pentuka laaro ojo Tusde ose to koja ladugbo Abiola Way si Oke Lantoro niluu Abeokuta nigba ti won lawon omo eleran ya bo okan lara awon osise ajo eso oju opopona, iyen VIO, ti won si luu lalubami.


VIO ti won fo lori
Gege b'AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago mejo koja iseju meedogun nisele bere to si gba won to bii wakati meji ki won too yanju e, to di pe won ko ara won lo sileese VIO to wa lagbegbe Post Office.

Ohun ta a gbo ni pe awon osise VIO la gbo pe won mu moto kan ti won ni iwe moto e ti diu (expire) laaro ojo naa, ti won si so fun okan lara won wi pe ko mu moto naa ati awako lo si Olu ileese won to wa ni Kotopo nitosi Camp laaro ojo naa.

A gbo pe se ni awako naa bere sii ba osise VIO naa soro wi pe ko gba (500) naira lowo oun, sugbon tiyen so pe ko si nnkan to jo o, sugbon nigba ti won so pe awako naa rii pe osise VIO naa ko fe e gba a, lo ba so o dija mon on lowo.

Nigba to maa de layipo (Round About) Abiola Way si Oke Lantoro, lo ba paaki moto e saarin titi, to si bere sii pe awon toogi lati wa a kona iya fun osise VIO naa, tawon yen naa ko si bere boro se je.

Omo eleran
A gbo pe won lu okunrin naa de bi to ku die ko daku, ati pe nigba ti won fo o lori, ti won si ti rii pe eje ti bere sii da lori e, ni won ba fese fee, sugbon ti okunrin VIO naa ko je ki awako naa salo mo oun lowo ko too di pe o bere sii pe awon eeyan e lati wa a gba oun sile.

Lesekese tawon yen ti de ni won ti so pe dandan ni kawon fese ofin muu, sugbon ko pe ti olori awon eleran to wa ni Abiola Way ti de lati ba okunrin naa bebe, sugbon toun naa tun n ba won lagidi.

Okunrin olori awon eleran naa, bo tile je pe ko daruko f'AWIKONKO so pe ka ni kii se pe won ti lu okunrin naa de bi ti eje bere sii da lori e, oun ko ba mo igbese toun maa gbe, sugbon kawon osise VIO lo se nkan to ba to fun un.

Lakoko isele naa
Lara awon osise VIO to tun b'AWIKONKO soro so pe okunrin naa ti koko bawon lagidi nigba tawon muu, to si n so pe omo egbe eleran to wa ni Odo Eran Abiola Way loun, sugbon ti won ni dandan ni ko gba iwe moto tuntun.



Lati fidi isele naa mule, ka si le mo ibi ti oro naa yori sii, akoroyin wa gbiyanju lati ba oga agba leka amuseya ajo naa, Ogbeni Taofeek Babalola soro, sugbon ti nomba e, 08033712403 ko lo titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI