Idi ti Gbemileke akekoo YABATECH se gbemi ara e lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 10, 2017

Idi ti Gbemileke akekoo YABATECH se gbemi ara e lojiji

Sunday Agbaje, Eko

Iyalenu loro iku akekoo jade ileewe gbogbonise Yaba College of Technology (YABATECH), Oluwamuyiwa Oluwagbemileke Sir-Muel si n je fawon ebi e, paapaa awon ore e lori bo se deede gbemi ara e lojiji lai so fenikeni.

Oluwagbemileke to gbemi ara e
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se fi ye wa, ana ojo Tosde ojo kesan an osu yi la gbo pe Oluwagbemileke to sese kekoo jade leka ikekoo Electrical and Electronics loo mu oogun oloro asekupakupani kan.

Oluwagbemileke ti won loun lomo keta tawon obi e bi, to tun je okunrin keji ninu ebi la gbo pe ko too di pe o gbemi ara e naa lo ti koko ko oro kan sori ero ayelujara abanidore kan wi pe beeyan ba n koju awon isoro kookan, oni lati mu okan le.

Ko seni to ti e koko fura lakoko naa, sugbon nigba to tun ko o wi pe kawon eeyan ba oun toju iya oun daadaa nigba toun ko ba si laye mo, lo fa a tawon kan ninu awon ore e ti n fura wi pe o seese ko ti maa dogbon kan labele.

Lara awon ore e ti won soro je ko di mimo fun AWIKONKO wi pe oro ile aye yi ti si oun, toun ko si mo ona toun fe e gbe e gba lati lu aluyo.

Titi di asiko ti a sakojopo iroyin yi tan la gbo pe mama e si fi wa ni ese kan aye, ese kan orun latari ironu omo e to deede gbemi ara e naa.

Ohun tawon eeyan n si ni pe ko ye ki Oluwagbemileke se nnkan to se yen nitori pe aimiye ireti lo si wa feni ti ko tii ku, sugbon ti aso ko ba omoye mo, nitori pe omoye ti rin ihoho woja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI