Oba Oniro sayeye odun keta lori ite pelu alaafia - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 22, 2017

Oba Oniro sayeye odun keta lori ite pelu alaafia

Nise lawon ojulowo omo bibi ilu Iro nijoba ibile Obafemi Owode, ipinle Ogun gba ilu ati sekere, ti won si bere sii korin idunnu ati ayo kaakiri ilu naa nigba ti won gbo pe ile ejo giga to fi kale si Isabo niluu Abeokuta so pe Oba Nojeemdeen Eyiowuawi Alani Adebari Ilufemiloye Obayemi gan gan ni ojulowo Oba Oniro.

Be o ba gbagbe, ojo ketala osu kewaa to koja la mu iroyin kan wa fun un yin wi pe Oba Oniro fe e sayeye odun keta lori ite, bo tile je pe Kabiyesi naa si wa nile ejo pelu esun ti won lawon olote kan ti ko gba ti e fi kan an.

Sugbon ni bayii, AWIKONKO gbo pe Oba Adebari Obayemi, Arolu 1 ti ri iwe ase gba, eyi to so pe ko ma a tesiwaju gege bi Oba ilu Iro pelu atileyin ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun.

Gege bi atejade kan to te AWIKONKO lowo losan oni Wesde ojo kejilelogun, eyi ti Adewunmi Dolapo to je alakoso foro ijoba ibile ati oye jije nipinle naa fowo si loruko akowe akowe ijoba fun eka ileese ijoba naa ipinu naa waye pelu ase ile ejo giga lojo kejidinlogbon osu keta odun yii.

Opo awon eeyan, paapaa awon ti won so pe olote ni won lo ti n ro pe ayeye odun keta naa ko ni wa saye lai mo pe ijoba ti gbe ase e jade, ti won si sayeye naa pelu ayo ati alaafia.

Ko too di pe ayeye odun keta naa bere la gbo pe ese ko fe e le gba ero mo ninu ilu Iro, tawon ero to n ya wole si fe e dabi ero Meka, titi ti won fi ayeye naa lojo kejila osu yii.

Oba Oniro wa a lo anfaani ayeye odun keta naa lati fi dupe lowo Alake tile Egba, Oba Adedotun Aremu Gbadebo fun akitiyan e pelu ife to fi gba won, o si tun dupe lowo awon ebi, paapaa idile to ti jade wa latari ipa tawon naa ko lori oro naa.

Bo tun se dupe lowo awon agbejoro e naa lo dupe lowo awon oniroyin fun iwadii ti won se, ti won si gbe eyi to je ojulowo iroyin ohun to sele jade sita lai fi igba kan bo okan ninu.

O loun ko ni ikunsinu tabi binu senikeni, yala awon to dide lodi sii, tabi awon to gbe awon eeyan dide lodi soun, bo tile je pe wahala naa koko fe e min oun, nitori to je nkan itiju ati ibanije, sugbon ti Olorun pada gbe oun bori nigbeyin.

Nigba to n dupe lowo awon omo Iro, paapaa awon to duro tii, o seleri fun won pe oun yoo sa gbogbo ipa ati agbara toun ni lati fi mu idagbasoke, isokan ati alaafia wonu ilu Iro lai pe nitori pe ife ilu Iro loun je oun logun.

Lara awon to wa nibi ayeye naa ni Olu Itori, Osolo tiluu Isolo, Ayandelu tiluu Odo, Akowe ileese ijoba to n soro Oba, Alaga egbe awako ti NURTW nipinle Eko atawon min in bii Sefiu Alao.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI