Ogogoro seku pa Chibuzor atawon meta nipinle Imo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 21, 2017

Ogogoro seku pa Chibuzor atawon meta nipinle Imo

Bunmi Adegbola

Iyalenu niku awon merin kan ti won so pe ogogoro lo seku pa won si n je fawon to gbo sile aburu naa lagbegbe Imerienwe nijoba ibile Ngor-Okpala, nipinle Imo, nitori ti won so pe kii soju lasan.

Ile igbafe kan to je ti gbajumo onisowo oti kan ti won pe ni Uwadiegwu Ezelmo ni won nisele naa ti ways lose to koja, ti won si so pe iwadii nnkan to sokunfa iku awon merin naa si n lo lowo.

AWIKONKO gbo pe, yato si Chibuzor Nwosu, Ifeanyi Nkwocha, Ada Danganer ati Friday Osuji to ku iku ojiji, sibe awon min in ti won le ni meje ni win si n gba itoju lati doola emi won.

Okan lara awon agbaagba lagbegbe naa, Ogbeni Agbara Emma nigba to n fidi oro naa mule je ko di mimo pe Chinonso Amadi, Nnadi Ike, Udoka Ukaegbu, Fineboy Ekeocha, Chiaka Ukaegbu, Onyemauche Igbo, Aboy Amadi atawon min in ni won si wa nibi ti won ti n gba itoju lowo.

O so pe ko pe tawon eeyan naa mu ogogoro naa tan ni won bere sii kegbe pe inu n run won, ti oro naa tun pada yiwo lojo Abameta Satide to koja.

Okan lara awon to n gbe agbegbe naa to ni ka foruko bo oun lasiri so pe lesekese tiroyin naa ti kan kaakiri ilu ni eni to ni ile igbafe naa, Ezelmo ti na papa bora, ti ko si seni to le so pato ibi to lo.

AWIKONKO gbo pe mosuari kan to wa ni Nguru, Ngor Okpala ni won pada gbe oku awon merin naa lo fun ayewo, tawon ti won si n gba itoju lowo wa ni osibitu kan to wa lopopona Egbu, niluu Owerri.

Titi di bi a ti n ko iroyin yi lowo ni agbenuso fawon olopaa ipinle naa, Ogbeni Andrew Enwerem so pe awon ko tii le fidi isele naa mule nitori latigba tawon ti gbo lawon ti n te DPO agbegbe naa laago, sugbon ti ko tii lo lati fidi e mule.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI