Ope o; awon odo orileede yi ti fe e bo saye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 27, 2017

Ope o; awon odo orileede yi ti fe e bo saye

Gbogbo eto lo ti fe e pari bayii lori bawon odo lorileede yii yoo se bere sii ri owo mu lo senu, ti won yoo si maa je ajeseku pelu bi olori ijo Treasure House of God ti olu ijo naa fikale siluu Abeokuta, Pasito Seye Senfuye se ti ranse sawon oluso aguntan egbe e atawon ileese nla-nla lagbaye lati wa a ro awon odo lagbara.

Gege b'AWIKONKO se gbo latenu alokoso foro iroyin ati bo se n lo ninu ijo naa, Ogbeni Adeniyi Adeloye, o so pe ipinu naa waye latari airi ise se awon odo lorileede yi, eyi to fa ki won maa banuje paapaa nipase eto orileede yi ti ko fese mule daadaa.

O so pe opo yanturu ni eto iro-lagbara naa yoo je fawon odo, lati ori awon akekoo, dori awon to kose owo lai fi oro eleyameya tabi oro oselu se nitori nkan to dara ju lo ni pe ki onikaluku le da duro laaye ara e.

Adeloye je ko ye eto naa yoo bere ni pereu ninu osu meta akoko odun 2018 pelu opo awon odo ti won yoo kopa lati je anfaani e, ti eto naa yoo si tun je olodoodun.

AWIKONKO gbo pe ipinu yi waye latari bi oro awon odo lorileede yi se je Pasito Senfuye logun, ti airise se won si n kan lominu pupo, ati pe ojo iwaju awon odo naa je logun pupo.

O wa rawo ebe sawon odo kaakiri orileede yi lati ma se foro ojo iwaju won sere, ki won si tete wa a je anfaani eto naa lati le je eni ti kii woju awon eeyan ki won to o jeun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI