ORO SUNNUNKUN PELU TAYO ADIO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 9, 2017

ORO SUNNUNKUN PELU TAYO ADIO

SE OMI INIRA LEYI NI TABI OMINIRA? (APAKEJI)

Mo ki gbogbo eyin ololufe Iroyin Awikonko, paapaa julo eyin ololufe ORO SUNNUNKUN. E ku ojo meji-meta kan, ajinde ara yoo maa je o. Ase Edumare.

Ti e ko ba gbagbe, nibi ti aba oro Ominira orileede Naijiria de lose to koja, ni bi ti a ti menu ba awon to ja takuntakun fun ominira orileede yi. Sugbon gege bi omo Yoruba atata, ati pe itesiwaju omo Oduduwa nipa igbelaruge otito ati awijare nile ati lokeere ni afoju sun Iroyin Awikonko wa fun, fun idi eyi e je ki a tun menu ba ipa takuntakun ti awon omo odua ko ninu igba ominira ile yii. Eje ka menu ba die ninu itan Oloye Obafemi Awolowo.

A bi Oloye Obafemi Jeremiah Oyeniyi Awolowo, ni ojo kefa osu keta odun 1909, si ilu Ikenne, nipinle Ogun. Nigba to di omodun meje ni baba to bi Obafemi Awolowo, iyen Oloogbe Pa David Sopolu Awolowo jade laye ninu osu kerin odun 1920. Oruko mama to bi ni Mary Efunyela. Obafemi lo sile iwe alakobere  St. Saviour School, Ikenne. O tesiwaju ninu eko re nileewe Baptist Boys’ High school, Abeokuta. Leyin to pari eko re ni o loo gba ise olukoni fun igba die, leyin eyi ni Obafemi lo ileewe Wesley College Elekuro to wa niluu Ibadan. O si tun fi igba die sise nileese itewe Nigeria Times.

Apa kinni: http://www.awikonko.com.ng/2017/11/oro-sunnukun-pelu-tayo-adio_2.html?m=0

Ko pe to tun fi tesiwaju lo sile  eko giga orileede London, nibi to ti keko gboye imose ni pa isowo (Bachelor of Commerce). Leyin eleyii ni Obafemi Awolowo lo si ile eko imo ofin orile ede London, to si di amofin ni ojo kokandinlogun osun kokanla odun 1946. Ni odun 1949, Awolowo da ile ise itewe aladani Nigeria Tribune sile nilu Ibadan.

Awolowo je eni akoko to koko ja fun eto ijoba eyi ti a mo si ‘’Federalism’’, eyi ti a ko ba tun maa pe ni ijoba elekunjekun.

Ninu ija ominira yi, Obafemi Awolowo loun fe ki omo Yoruba je okan pataki ninu awon omo igbimo orileede Naijiria, to si pinu lati da egbe omo Oduduwa sile, iyen (Action Group). Fawon to ba mo Awolowo daadaa, won a mo pe ko fi oro eko sere rara, nitori idi eyi lo se da eto eko ofe fun awon omo ile Yoruba kaakiri aye. Bee ninu agbega ti Baba Ikenne gbe wo ile Yoruba ati gbogbo ile Adulawo ni ile ise amohunmaworan akoko nile Adulawo, eyi to wa niluu Ibadan.

Eyi nikan ko, nitori pe Awolowo je okan pataki ninu awon to da ilese Akojopo omo Odua (Odua Group) sile, ninu eyi ti won ti se ikowojo fun kiko ile to ga ju lo ni gbogbo iwo oorun ile Afrika (Cocoa House).

Awolowo ni Premier akoko fun gbogbo ile Yoruba, nigba to tun di odun 1956, won tun dibo yan fun igba keji gege bi Premier, sugbon ni ojo kejila osu kejila, odun 1959, ni won dibo yan gege bi Asoju-sofin fun aarin gbungbun orileede yii, nibi to ti di olori awon egbe alatako. Awon ara oke-oya ri egbe alatako ti Obafemi tuko re gege bi ota to foju han, fun idi eyi nigba to di osu kesan odun 1963, won fi esun idalu ru kan an, won si da ejo ewon odun mewa fun Oloye Obafemi Awolowo.

Nje e mo eya ti adajo to ju Oloye Obafemi Awolowo je, ati pe kinni in oruko re?
Se Awolowo lo odun mesan lewon?
Nje kin in ni ti oro Oloogbe Oloye Akintola ninu oro yii?
Eyin ololufe Iroyin Awikonko, e je ka pade ni ose to n bo lati tesiwaju.

Adio Tayo Ibrahim
08105088418No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI