Onarebu Najimudeed
Abolaji Abass tawon eeyan tun mo si Gbayawu ti sapejuwe Gomina ipinle Oyo, Isiaq
Abiola Ajimobi gege bi akinkanju okunrin, ti kii beru lasiko ogun, paapaa fawon
ise arambara olokan-o-jokan ati idagbasoke ti ko lafiwe to ti se nipinle Oyo.
Onarebu Abass soro
naa ninu atejade to fi ranse s’AWIKONKO lati fi gboriyin fun Gomina Ajimobi fun
ti ayeye ojo ibi odun mejidinlaadorin (68) e.
Onarebu Abass to je
alaga fidihe nijoba ibile Ibadan South Local East Government, to tun je
oludasile ati Aare ajo Achievers’ Group Patron; Awolowo Wheel of Oasis
Organisation so pe ipa ti Gomina Ajimobi ti ko nipinle naa ko lafiwe.
Ninu oro e lo ti so
pe idunnu nla lo je foun lati mo Gomina ipinle Oyo naa, to si tun je adari ti
ko lafiwe. O so pe opo ise manigbagbe ni Ajimobi ti se sipinle naa, tawon eeyan
si n pokiki e kaakiri agbaye.
O tesiwaju pe opo
awon eeyan nipinle Oyo, paapaa lorileede Naijiria ni won ti ti ara Ajimobi di eeyan
alalubarika lawujo, ti won si tun n gbe nkan meremere se.
Abass so pe Olorun
lo yan Gomina Ajimobi fawon nipinle Oyo latari awon idagbasoke ati itesiwaju
alailegbe to ti mu wo origun mereerin ipinle naa, to si je pe kaakiri agbaye ni
won ti n kan saara si fawon ise akanse naa.
Onarebu naa wa a gba
a ladura pe oke-oke ni Gomina Ajimobi yoo maa lo, ti ko si nii wale lailai. O ni
igba odun, iseju aaya kan soso ni fun Gomina Ajimobi.
He has taken his own share. Ode ati ole ni gbogbo won.
ReplyDelete