Leyin osu meje:Oba Eleko ati Ooni Ife pari ija nibi ayeye igbade Akarigbo tile Remo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 11, 2017

Leyin osu meje:Oba Eleko ati Ooni Ife pari ija nibi ayeye igbade Akarigbo tile Remo



Titi di bi e ti n ka iroyin yi loro Oba Eleko, Riliwan Akinolu ati Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi si fi n ya awon eeyan lenu lori bawon mejeeji se pari aawo to wa laarin won nibi ayeye igbade ati opa ase, pelu iwe eri Akarigbo tile Remo tuntun, Oba Adewale Ajayi to waye ni papa isere Sagamu International lojo Tosde ose to koja yii.

Be o ba gbagbe, ninu osu kerin odun yi ni fonran kan jade sori ero ayelujara nibi ti Oba Rilwan Akinolu ti yeye Ooni Ile Ife nibi ayeye kan to waye niluu Eko, to si mu kawon eeyan maa so orisirisi oro si Oba Akinolu nipa iwa naa.

Bo tile je pe lesekese ni Oba Akinolu ti soro jade wi pe oun ko to be e lati yeye Ooni Ile Ife, ati pe asa Ilu Eko loun fe e ko pada latari bi won se n ki ara won, sugbon tawon eeyan n so pe iro ni Kabiyesi naa n pe nnkan to fe e se lo wa ninu e.

Latigba naa lawon mejeeji ko ti foju kan ara won mo, nitori ti ode ariya ko pa won po, bo tile je pe a gbo pe Oba Akinolu ti n wa ona lati be Ooni fun nkan to se naa.

Sugbon nise ni nnkan yi pada lojo Tosde to koja yi tawon eeyan si bere sii korin 'ija dopin, ogun ti se' lai si ni soosi, nigba ti won ri bi Ooni Ile Ife naa, Oba Ogunwusi ati Oba Akinolu se di mo ara won, ti won si tun soro fun bii iseju merin.

AWIKONKO gbo pe Oba Akinolu lo ti koko de sibi ayeye naa, sugbon nigba ti Oba Ogunwusi de si gbagede naa ni nnkan aabo kan ku iseju mewaa lawon eeyan ti n woye boya awon mejeeji yoo ki ara won tabi ki Oba Akiolu tun se bo se se lojo si, to foju pa Ooni re.

Iyalenu lo je pe bi Ooni, Ojaja keji se gun oke lati loo jokoo sibi aaye ti won ti lese sile fun un legbe Akarigbo tuntun naa, ni Oba Eleko ti sare dide legbe Alake tile Egba, Oba Gbadebo lati loo ferin pade e, ti won tun di mo ara won fun bii iseju aaya mewaa (10second), tawon toro naa soju e si patewo fawon mejeeji.

Iyen ni kan tun ko, leyin yen lawon mejeeji tun foro jomitoro oro fun bii iseju merin, ko too di pe won pe Oba Adedotun Aremu Gbadebo lati ba won da si oro ti won n so, leyin naa ni Ooni tun ki awon to wa nibe, to si loo pada jokoo.

AWIKONKO gbo pe ohun tawon eeyan n so ni pe wahala to teyin iwa ti Oba Eleko hu lojo naa lo fa a to fi n wa gbogbo ona lati fi pana e, sugbon ti Adura e pada gba leyin o reyin.

Nigba to n soro, Oba Enitan Ogunwusi so pe isokan ati alaafia lo ye gbogbo omo adulawo paapaa eya Yoruba, nitori naa ki a lo ife lati fi gbe esin, asa ati ise abalaye wa laruge.

O je ko di mimo pe inu oun dun gidigidi lojo naa nitori pe ojo naa je gege bi ojo toun naa gbade gege bi Ooni Ile Ife.

Ninu oro igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo lo ti gba Oba Adewale Ajayi lamoran wi pe ko rii daju pe o lo ipo e ati imo ofin to ni lati mu alaafia wo ile Remo, ko si ife bawon eeyan e lo.

Nigba toun naa n soro, Oba tuntun naa so pe oun dupe gidigidi lowo ijoba ipinle atawon igbimo to sagbateru ayeye naa fun ona ti ayeye naa gba waye.

O wa a gba ijoba lamoran wi pe ki won rii daju pe won wa iyanju si airise se awon odo, paapaa awon to n kekoo jade lodoodun, toun naa si seleri wi pe ayipada rere yoo wo ilu Remo paapaa ipinle Ogun lasiko toun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI