Obasanjo fi orogbo ati obi pari PhD e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 11, 2017

Obasanjo fi orogbo ati obi pari PhD e

Gbogbo awon to ri Aare tele ri lorileede Naijiria, Oloye Olusegun Okikiola Obasanjo nibi to ti n difendi iwe eri PhD to sese pari yi pelu orogbo ati obi ni won ti n ki baba na ku oriire, ti won si n so pe ko si iye odun teeyan ko le fi kawe.

Bo tile je pe ohun tawon kan n so ni pe Oloye Obasanjo to tun je Ebora Owu, eni tawon United Nation sese fi je alaga igbimo to n gbani lamoran lagbaye (Chairman, Adviser to the United Nations) ni nnkan bi osu meji seyin ko le kawe naa yori nigba to gba foomu naa ni bi odun meloo kan seyin, sugbon ti oro naa ti wa a yi pada bayii.

Ileewe giga ti Nou, iyen National Open University ni baba naa ti bere giga e, ko to o tun gba foomu PhD ni nnkan bi odun meta seyin, sugbon tawon eeyan ro pe OBJ ko le pari e, ti oju si ti wa a ti awon ti won ro pe ko le pari e bayii.

Aworan foto Baba Obasanjo lo bo sori ero ayelujara lose to koja yi nibi to ti n difendi eko PhD naa, pelu orogbo, obi ati tomtom, tawon eeyan si n so orisirisi oro to dara sii wi pe o farabale daadaa.

Bo tile je pe ko seni to tii le so pato lori koko tabi akole ti Oloye Obasanjo sise iwadii le lori, ko to  wa a soro lori e naa, sugbon ta a gbo pe aimoye osu lo fi sise iwadii naa.

Ohun tawon kan n so ni pe, Obasanjo ko gbe ara e ga wi pe oun ti je Aare orileede ri, toun ko si ni oye min in lati gbe apoti e, to le mu ko tun pinu lati kawe siwaju sii.

Eyi gan an lo tun fawon kan lanfaani lati bu enu ate lu awon odo to pinu pe awon ko le kawe mo, ti won si wa n fi ti Obasanjo sapere fun iru awon odo bee.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI