Odaju abiyamo ri omo e mole laaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 11, 2017

Odaju abiyamo ri omo e mole laaye

Ko si abiyamo tooto to gbo nipa iroyin obinrin kan to loo ri omo e, omo osu meta mole lai tii ku, tomo naa si se be e gbabe ku, ti ko maa sepe nla nla fun un, nitori ta a gbo pe ojulokokoro owo lo sun un de be.

Ojo Abameta Satide to koja lo lohun la gbo pe isele naa waye ni ilu Agbavi, orileede Togo, sugbon towo palaba e pada segi lojo Aje Monde to koja yii.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni odaju abiyamo yi ti a ko tii mo oruko e titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan lo sese pade baba olowo repete kan to ti seleri fun un lati fe e sile gege bi iyawo tuntun.

Baba olowo naa la gbo pe o so fun obinrin naa to n tomo osu meta lowo yi wi pe to ba fe koun fe e tokan tokan lai si idiwo, a fi ko loo wa bo se maa se omo owo e, nitori pe oun ko le maa toju omo ti kii se toun.

Odaju abiyamo yi la gbo pe omo owo e nikan eni to fun un loyun gba, nitori to so pe ko si adehun fife laarin won, ni ko ronu wi pe koun loo gbe omo naa fawon ebi eni to fun un loyun, to je pe nise lo lo o ri omo naa mole laaye.

AWIKONKO gbo pe bi won se n beere lowo odomobinrin yi wi pe nibo ni omo e wa lo n so pe oun ti gbe e lo sodo awon ebi baba e lati maa toju e nitori toun ti ri ololufe tuntun.

Awon araadugbo to n gbe la gbo pe o loo ta baba omo naa lolobo pe ki won sewadi ibi to gbe omo sii nitori ti ara n tu awon sii, eyi lo fa ti won ni okunrin naa fi gba ile e lo lati loo beere omo naa lowo e.

Ohun ta a gbo ni pe obinrin yi ko ri oro gidi kan so, lo fa a ti won fi loo foro e to awon olopaa leti, ti won si te e ninu daadaa, ko too di pe o pada jewo fun won pe oun loo sin in, ati pe ki won dariji oun.

Nigba ti won maa fi de bi to sin omo kekere yi si, o ti ku patapata. Lesekese lawon olopaa si ti gbe e lo si tesan won nibi to ti jewo fun won pe baba olowo toun sese pade lo so pe oun ko le fe e pelu omo owo oun.

Titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan la gbo pe won ko tii ri baba olowo naa lati foro wa a lenu wo, nitori ta a gbo pe lesekese tiroyin naa ti te e lowo lo ti na papa bora.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI