Leyin Odun Meji, Kasnaty Soro Lori Redio Sweet FM - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 27, 2018

Leyin Odun Meji, Kasnaty Soro Lori Redio Sweet FM

Bo tile je pe opo awon ololufe gbajumo aderinposonu sorosoro nni, Ogbeni Kolawole Atanda Adejojo topo mo si Kasnaty ni won ti n beere lowo e nipa idi ti ko fi seto lori redio Sweet FM, 107.1 to fikale siluu Abeokuta latigba ti won ti da a sile lodun 2016, sugbon ta a gbo pe nkan to n so fun won ni pe ko si nkankan, ati pe tasiko ba to, oun yoo bere.

Kasnaty

Oro naa yipada lonii ojo Abameta Satide nigba ti Kasnaty tawon eeyan tun n pe ni Oko Ifokanbale wole sori eto kan, ti okan lara awon omose e to ko nise maa n se lojo Satide, iyen Agbo Miliki ni deede aago mefa kuseju mewaa irole, to si bere sii soro.

Bokunrin to je ariimojukuro fawon obinrin, ko da, tawon okunrin gan an tun un ko o je se bere sii soro lawon to tan redio won lasiko ti bere sii ranse sira won wi pe ki won gbo redio Sweet FM, Kasnaty lo n soro nibe.

Ko seni to gbo awon ijinle oro ti Kasnaty to fodun bii metala ko ise sorosoro lowo agba sorosoro nni, eni to tun je Aare egbe awon sorosoro to da duro, iyen Freelance Broadcasters lorileede Naijiria, Ogbeni Yemi Sonde, tawon eeyan tun mo si Jigan Akala (Ekun, Oko Iya Ife) ti ko kan saara sii.

Gege b'AWIKONKO se gbo, opo awon ololufe Kasnaty to ti ro pe okunrin naa seto naa pari di aago meje irole ni won tun n binu wi pe asiko to lo ko ju iseju mejilelogun (22minutes) lo, ko to o gbe baagi e.

Ko si nkan meji to je kawon eeyan gbadun eto naa ti Kasnaty fi iseju mejilelogun tuko e, bi ko se ona to maa n gba lati se awon eto e tele, iyen ona to ti ko sile to fi pada seto naa.

Kasnaty nigba to n soro lori bo se bere so pe aimoye nkan loun farada lodo oga oun, Jigan Akala, sugbon toun wa n ko eere (profit) e lonii, toun ko si le gbagbe Yemi Sonde to je awokose (mentor) oun.

O wa a dupe gidigidi lowo omo e tele naa fun bo se pon oun le, to si foun lasiko toun fi soro lori redio naa. Bee lo ki oludasile atawon alakoso Sweet FM bi won se n tuko ileese naa.

Leyin eto naa lawon kan ta AWIKONKO lolobo wi pe opo awon ololufe e ni won ti pe e wi pe ko pada sori owo to fi seto lonii, nitori pe oun lawon fi n gba ti e nigba to koko bere, pelu awon asayan ede e, sugbon to ti pa won ti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI