Won ka oku omo kekere mo Emmanuel lowo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 4, 2018

Won ka oku omo kekere mo Emmanuel lowo

Bi kii ba a se pe awon eleyinju aanu tete gba okunrin kan eni odun mejilelogoji (42) ti won poruko e ni Ajiboye Emmanuel Olusola ti won ka Oku omo kekere mo lowo lojo Fraide ose to.lo lohun ni gaaraji Sapade nipinle Ogun, o see se ko ti dero orun alakeji nitori pe die lo ku ki won dana sun un.

Ohun ta a gbo ni pe ipinle Kwara ni Emmanuel ti n bo, to si n lo siluu Eko ko too di pe asiri e tu sawon araalu lowo lakoko to fe e moto ni garaaji Sapade, ti won si pariwo e sita.

Gege b'AWIKONKO se gbo, ni bo tile je pe ko seni to fura sii pe oku omo lo wa ninu baagi to gbe dani nitori ona to fi gbe e , sugbon nigba ti oku naa bere sii run, ti oorun naa si ti koja afarada fawon eeyan to wa ninu moto to wo ni won pariwo lee lori wi pe ko bo sile.

Ka ni o mo pe asiri oun maa pada tu ni, o see se ko ti bo sile lati wa ona min in to maa gba de ilu Eko to n lo nigba tawon n pariwo lee lori wi pe ko lo gbe nkan to wa lowo e sonu sinu igbo, toun naa si sori kunkun.

Nigba tinwon beere lowo e pe ki lo wa ninu baagi naa, nkan to so fun won ni pe ajeku ounje lo wa ninu e, ati pe oun fe e gbe lo fawon eran oun ni, awon to fura sii ni won so fun un pe ko je kawon ye e wo, sugbon to ni ko si nkan to jo.

Nigba ti won rii pe okunrin naa ko fe e bo sile, ti ko si fe kawon eeyan wo nkan to wa ninu e, ni won ba baa se lagidi, ti won si fa baagi naa ja mo lowo, nigba ti nkan to wa ninu e maa fi bo sile, lo ba di oku omo kekere.

Iyalenu lo je fawon to wa nibe ti won si bere sii luu nilukulu wi pe okan lara awon gbomogbomo to maa nnji omo gbe fi soogun owo ni, ati pe o see se ko je pe omolomo lo lo ji gbe lati loo ta a fawon to ran nise.

Nigba ti won beere lowo e pe nibo lo ti rii, nkan to so ni pe omo oun ni, ati pe ose naa lo ku, ko sii sibi toun le sin in si, lo je koun pinu lati loo sinku e silu Eko, nitori pe Offa loun ti n bo.

Emmanuel so pe kasiri oun ma baa tu lo je koun gba Sapade lati lo silu Eko, sugbon gbogbo bo se n soro naa ni won so pe iro lo n pa, ati pe awijare lori asan lo n wa.

Lesekese la gbo pe awon to wa nibe ti bere sii luu, ko to o di pe awon kan tete ranse sawon olopaa to wa ni Isara lati fi to won leti, tawon naa ko si foro naa para ki won too lo.

Alaye ti won lokunrin naa tun se fawon olopaa ni ko te won lorun, ti won si gbe e lo si tesan won lati loo tesiwaju nipa iwadii won.

Agbenuso fawon olopaa, Abimbola Oyeyemi je ko di mimo pe Komisana won, Ahmed Iliyasu ti gbo soro naa, o si ti pase pe kawon olopaa to n ri soro apaayan gba ise iwadii naa se.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI