Ole alapa masise ko le je oye laafin – Agura tiluu Gbagura - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 1, 2018

Ole alapa masise ko le je oye laafin – Agura tiluu Gbagura

Oba Halidu Adedayo Olaloko, Agura tiluu Gbagura ti so pe eeyan ti ko nise lapa ko le je oye to ba kere ju, paapaa oye Balogun laafin, nitori pe ko ni bojumu ki oloye ma le se awon eto to ba ye ki iru oloye bee se laafin.
Oba Agura
Oba Agura lo soro yi lonii, Ojobo Tosde ninu gbongan aafin e to wa niluu Gbagura lakoko to n fun Oloye Biobaku Alao Taofeek Bakare niwe eri ati opa ase gege bi Balogun tiluu Ijaye Obirinti tiluu Gbagura.
Kabiyesi so pe aye atijo ni won ti n fi awon ti ko nise lapa atawon eeyan lasan je oye laafin, sugbon pelu olaju to de lasiko ta a wa yi, eeyan lasan ko le je oye mo laafin, paapaa eni ti ko ba ti lowo lowo, nitori pe eni ti won ba fi je oye gbodo je eni to lowo lowo lati se awon eto to ba ye ko se laafin ati lawujo to ti je oye.
Bee lo so pe oloye nikan lo maa n ku, sugbon ti oye wa titi lai, ati pe bi oloye kan ba ti papoda, o di dandan ki won yan oloye min in lati di oye naa, eyi lo so pe o lo nibamu pelu bi won se yan Oloye Biobaku gege bi Balogun tuntun fun ilu Ijaye Obirinti lati ropo Balogun ana to papoda.
Kabiyesi tesiwaju pe bi won ko ba tete yan oloye min in lasiko to ba ye, esinsin-kesinsin maa ba le oye naa, tawon eeyan yoo si maa ja si lati je e, eyi to si le sakoba fun ilosiwaju ati idagbasoke ilu naa.
Ninu oro e, o so pe “Gbogbo wa la mo wi pe oye kii ku, bi oloye kan ba ku lonii, elomin in a tun je. Ko si oloye ti ko le je oye mejo, nitori pea aye si sile fawon oloye lati je oye to ba wu won.
“Abiola lo koko bere e, bo se je oye l’Egba, bee lo je n’Ibadan atawon ilu min in kaakiri. Mi o lodi si eni ti mo fi je Balogun Ijaye Obirinti lonii, emi to ba si je oye lo maa lo o lalope.
Balogun tuntun
“Olowo lo n je oye lasiko yi, nitori pe ko bojumu kawon ti ko je oye laafin maa da owo tasiko lati da owo ba ti to, ko wa je pe Balogun lo maa pin owo naa, lai je pe oun naa da owo.
“Eni to maa tun ilu se lo n je Balogun. Bi won ko ba si tete je e, esinsin-kesinsin yoo ba le e. Mi o fe ko ma a lo so kaakiri wi pe oun ti je oye Balogun lai je pe mo jokoo laarin eyin ilu lati fi onte si, ki n si so fun un yin wi pee mi ni mo fi je Balogun, ki awuyewuye ma ba a teyin e yo lojo iwaju.
“Ko seni ti ko le je oye Balogun, sugbon eni to ba maa je gbodo sise de be, ko to o di pe won yan an sipo.”
Nigba to n soro, Balogun Ijaye Obirinti tuntun naa, Oloye Biobaku Bakare dupe lowo Oba Agura tiluu Gbagura fun anfaani to foun lati je oye Babanla oun, ati pe oun ko ro o ti tele wi pe oun le je oye naa, bo tile je pe kii se oye akoko toun maa je ni Balogun toun sese je naa.
O ni oye naa dun mo oun ninu pupo nitori oye ilu oun ni, ati pe ilosiwaju, alaafia ati isokan ilu naa lo je oun logun, pelu bi oye naa tun se je oye asiwaju ilu, oye to je pe oye to n wa alaafia ati ilosiwaju ilu ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI