Aregbesola fe e gbe ileese telifisan NTA lo sile ejo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 24, 2018

Aregbesola fe e gbe ileese telifisan NTA lo sile ejo

Bo tile je pe bi ere lawon kan ro bi oro naa nigba ti won gbo pe ijoba ipinle Osun labe Gomina Rauf Aregbesola loun fe e gbe awon ileese to je gbese owo ori lo sile ejo, sugbon ti oro naa ti wa a pada di otito bayii.

Gege bi a se gbo, won ni opolopo ileese nla-nla to fi mo ileese telifisan ijoba apapo orileede yi, iyen NTA atawon ileese aladani ti won je ijoba ipinle naa ni gbese obitibiti owo ori to le ni milionu naira nijoba ti setan lati foju won ba ile ejo.

Nigba to n fidi iroyin naa mule, oludamonran pataki fun Gomina Aregbesola nipa owo ori ati eto ipawo wole labenu, Ogbeni Olugbenga Akano so pe gbogbo akitiyan won lati bawon onileese naa soro lati san gbese won lo ja si pabo.

Lara awon ileese naa ni NTA lle-Ife (N6, 734,886); Globacom Nigeria Limited (N7,600,595); O.A.U (N1,844,770); SAMMYA NIGERIA LIMITED (N5,002,567); WETLAND CONSTRUCTION NIGERIA LIMITED (#8,686,336); 9Mobile (N882,458,475).

Awon min in ni Nigeria Custom Services (N111,221,381); Nigeria Security and Civil Defense Corps (N128,289,909); Nigeria Prison Services (N44,567,867); Center for Energy Research and Development (N42,393,130); LAPO AGRIC DEVELOPMENT (N7,078,313) ati ileese KABASON GLOBAL INVESTMENT LIMITED (N13,566,399).

Akano tenumo on pe ijoba ti setan bayii lati gbe gbogbo won lo sile ejo ti won ba kuna lati san gbogbo owo ti won je laarin ojo meje pere.

O je ko di mi mo pe gbogbo gbese naa leyin tawon pa a po tan je bilioonu mejila ataabo naira.

Ninu oro tie, komisanna feto iroyin, Ogbeni Adelani Baderinwa so pe o nira fun ijoba lati pawo wole labenu lai rogboku le owo to n wole lati odo ijoba apapo.

O ni enikeni to ba kuna lati san owo ori gbodo mo pe oun ti se lodi si agbekale ofin, eleyii to ni o ni ijiya e labe ofin iwa odaran lorileede yii.

Source: AGBALA IROYIN

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI