Irorun Ti De Fawon Osise Feyinti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 19, 2018

Irorun Ti De Fawon Osise Feyinti

Bi e se n ka iroyin yi lowo la gbo pe gbogbo eto ti pari fun ti idanilekoo olojo kan soso ti ileese Business Development and Support Services pelu ajosepo Business Executives International gbe kale fawon osise feyinti pelu awon osise to n gbaradi fun ifeyinti won lori awon ona ti won yoo ti maa ri owo jaburata leyin ti won ba feyinti.

Ojo Abameta Satide to n bo yi, iyen ojo kokanlelogun osu yii (Saturday, April 21) ni idanilekoo naa fe e waye ni soobu itaja igbalode ti Atobatele to wa ni Imo, niluu Abeokuta (Atobatele Complex, 68, Awolowo Avenue, Imo Abeokuta, Ogun State) lati aago mewaa aaro.

Kii se iroyin tuntun mo pe ipolongo idanilekoo olojo kan soso ti n lo kaakiri ori redio, telifisan ati ori ero ayelujara, paapaa lori iroyin AWIKONKO lati bii osu meloo kan seyin, tawon eeyan si ti n gbaradi fun un.

Idanilekoo naa ti won pe akori e ni Pataki Ifeyinti Ninu Eto Oro Aje To Ni Adojuko, iyen ni pe Essence Of Retirement In A Challenged Economy ni won lawon ojogbon lorisirisi eka ise ni won n bo lojo naa lati wa a si oju awon araalu, paapaa awon osise feyinti si awon ona ti won yoo gba lati maa ri owo.

AWIKONKO tile gbo pe kii se pe won fe e fi eto idanilekoo naa pawo wole, nitori pe ofe (free) lawon eeyan yoo wole sinu gbongan ti eto naa yoo ti waye, ti won yoo si kogbon orisirisi nibe ki won to o maa lo sile won.

Ohun ta a tun gbo pe o fa a ti won fi gbe eto kale ni lati mu adinku ba bi awon osise feyinti se maa n lo lati jokoo senu ona ileese ti won ba ti feyinti lati gba  ifeyinti won, to si je pe se ni won yoo maa fi oni-d'oni, f'ola-d'ola fun won.

Ogbeni Kolawole Adejojo tawon eeyan tun mo si Kasnaty to je gege bi agbenuso fun ileese naa nigba to n b'AWIKONKO soro lai pe yi so pe ko seni to maa debi idanilekoo yi lojo Satide, iyen otunla ti ko ni maa dupe nigba tiru eni bee ba gbo awon ona ti owo jaburata fi ma maa wole fun un.

Okunrin gbajumo sorosoro naa tun je ka mo pe lara awon nnkan ti won fe e dawon eeyan lekoo lori e lojo naa ni Bi a se le gbe igbese lati wonu ifeyinti (How to plan your retirement), Gbigbarukuti ise okoowo ati oro iyanju (Business Support and Advice) ati Lila awon eeyan loju sawon anfaani to wa ninu okoowo (Exposure to Opportunities in Business and Investment).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI