OSELU AWAARAWA LO JE MI LOGUN - Kay-Plenty - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 8, 2018

OSELU AWAARAWA LO JE MI LOGUN - Kay-Plenty

Okan lara awon oludije sipo kanselo, ni woodu Asero, ijoba ibile Abeokuta South lodun 2016, Onarebu Oluwakayode Oladipupo ti so pe oselu awaarawa lo je oun logun ju ninu eto isejoba to wa nita lakoko yii.

Onarebu Oladipupo to n foju sona lati jade dupo okan lara awon omo ile igbimo asofin lati ekun Abeokuta South labe egbe oselu Accord ninu idibo odun 2019 to m bo lona lo soro yi lakoko to n b'AWIKONKO soro niluu Abeokuta lai pe yii.

Oladipupo tawon eeyan tun mo si Kay-Plenty so pe o seni laanu pe opo awon ti won pe ara won ni oloselu lo je pe won ko bikita lati wo eyin wo, ki won saanu awon to dibo yan won sipo, to je pe apo ara won ni won n ja fun.

Bakan naa lo tun so pe 'bi a ba s'eni loore' ope la a n du', eyi gan an lo so pe o ye ko je orin tawon oloselu tawon araalu ba fi ibo won gbe wole maa ranti ni gbogbo igba, nitori pe eto awon araalu lodo ijoba, yala ijoba apapo, ipinle tabi ibile ni nnkan ti won n reti gege bi ope, sugbon won kii ro o be.

Gbajumo oloselu naa ni imo tara eni nikan lo po ju ninu awon oloselu ta a ni lasiko yii, paapaa awon ti won pe ara awon ni agbalagba, ti won ko fe e ki awon odo de ijoba, bo tile je pe orin asiko odo la wa ni n ko, sugbon ti ko de inu won.

O ni ipinu oun lati jade dupo omo ile igbimo asoju-sofin nipinle Ogun ni lati gba awon eto awon araalu fun won, ki eto isejoba awaarawa ti a tonn pariwo lati odun to ti pe seyin le tete wa si imuse.

Ninu oro e, o so pe "Onikaluku lo ni ipinu e lati gbe igbese. Ipinu ti mo se lati fe e jade dupo omo ile igbimo asoju-sofin nipinle Ogun ni lati je ki eto isejoba awaarawa fese mule, kawon araalu le je igba dun mudun-mudun eto ijoba alagbada.

"Pupo ninu awon omo ile igbimo asofin lo je pe ase ni won n tele, to je pe owo nikan ni won mo lati pin, ti won kii ronu pe awon kan lo fi won sibe, lati wa a mu awon ileri ti won ti se fun won lasiko idibo se.

"E ma je ka tan ara wa, oju ti la, asiko ti to lati gbajoba lowo ijoba amunileru APC yi. Fun awon to ba si le ranti daadaa lakoko ipolongo idibo odun 2015, opolopo ileri ni ijoba APC se fawon araalu, me lo ni won ti se, me lo ni won ti pari.

"Egbe oselu PDP ti se e, a si ti ri bi won se se e. Egbe oselu APC lo n se lowo yii, oju wa ko fo pelu ibi ti won n ti wa lo. E je ka gba egbe oselu ACCORD laaye lati wo bi won se fe e se e, nitori pe bi a ko ba tii to obe wo, a ko le mo bi o se dun to, bo ya iyo po ju ninu e ni, tabi epo ko to.

"Orisirisi egbe oselu lo maa dide lodun 2019, sugbon egbe oselu ACCORD yato si egbe oselu oniro, eletan, amunileru. E je ka gba awon odo laaye lati sejoba orileede yi. Aare teleri lorileede yi, Oloye Olusegun Obasanjo, ko tii pe ogbon odun nigba to je Aare orileede yi, ki lo wa a de ti awa odo ko le dide lati gba eto wa."

Nigba to n soro nipa awon aseyori gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun, Kayode Oladipupo so pe lai fi igba kan bo okan ninu, Gomina Amosun gbiyanju agbara e lati mu ayipada ba ipinle Ogun, sugbon ti asiko lati soro ko tii to.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI