Awon maketa lo le mi kuro nidi ise tiata – Baba Wande - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 8, 2018

Awon maketa lo le mi kuro nidi ise tiata – Baba Wande

Aanu aje yoo fe e le seeyan bo ba gbo bi gbajugbaja agba oni tiata nni, Alaaji Kareem Adepoju topo awon eeyan mo si Baba Wande se n soro, to so pe awon maketa ni ko je koun ti gbe sinima jade, nitori pe se ni won le oun danu tefe-tefe.


Lose to koja yi ni Baba Wande b’AWIKOKO soro niluu Abeokuta, to si fe e le maa yo omi loju lakoko to n dahun ibeere olokan-o-jokan paapaa bo tun se sa seyin nidi ise tiata, ti ko si tun ti gbe sinima jade bii ti tele mo.
O ni opo fiimu tawon n gbe jade lo je pe owo ele lawon lo n ya lati fi se e, igba tawon ba si pari e tan lawon maketa yoo tun je awon lowo, ti won ko nii san owo fun won, to je pe se lawon yoo tun sese maa gbe ara won lo sile ejo kawon too le ri owo won gba diedie.
Ninu oro e, o so pe “Mi o le si se fiimu mo fawon maketa, nitori pe mi o le loo ya owo fi se fiimu lai jere e. Ki nni yoo je eere mi, nigba ti mo ba se fiimu, ti mo gbe e fun maketa, to je pe se ni won a tun je mi lowo, ti mi o pa owo lori e. Nigba ti a ba ta fiimu, ti a ko ri owo gba, to di pe a bere sii gbe ara wa lo sile ejo. Mi o tun le loo ya owo fi se fiimu jade mo, ko wa je pe maketa lo maa je gbogbo eere to wa nibe to ye ki n je.
“Won yan mi je ninu fiimu Ti Oluwa Nile, to je pe awon ta a jo se e lo jeere e, won ko je ki awa ta a kopa to joju jeere e. Eyi ta a tun se funra wa, awon maketa tun je wa lowo. Kii se oro awon to n se ayederu ni won ko je ka jeere rara, eyi ti awa arawa n se funra wa lo po ju, ko da to ju ti awon to n se ayederu lo. Ijoba ko le da si, nitori pe ijoba gan an mo nnkan to n sele.
“Mo dupe pe latigba ti mi o ti se fiimu jade, ebi ko pa mi. Mo tun ti n dogbon lati ya ise min in, ki n si ta a funra mi, ko da, Olorun tun ti fi ona tuntun han mi lati maa gbe fiimu jade funra mi. Ori ero ayelujara ni opo fiimu mi yoo maa wa, iyen lori Baba Wande TV ni YouTube.”
Nigba to n soro isokan laarin awon oni tiata elegbe e, o ni ayipada rere ti n wa nitori pe leyin ti Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi ti ba won da si lodun to koja lawon ti n ba ara won se po pada bii ti tele, ati pe oun ati Dele Odule tun ti pada di ore, tawon ko si le se kawon ma soro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI