AWON ODO NAIJIRIA LAWON KEYIN SAWON AGBAAGBA NIDI OSELU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 29, 2018

AWON ODO NAIJIRIA LAWON KEYIN SAWON AGBAAGBA NIDI OSELU


Lonii ojo kokandinlogbon osu karun un, tii se ojo ayajo ayeye eto isejoba awaarawa lawon agbarijo odo lorileede Naijiria, eka tipinle Ogun labe asia egbe Ogun Youth Alliance lawon ti keyin sawon agbalagba nidi oselu to n dari orileede yi. 

Awon odo naa, ti Komureedi Sodeinde Daniel lewaju won la gbo pe won se iwode (rally) kaakiri ilu Abeokuta tii se olu-ilu ipinle Ogun lati fi saami ayeye eto isejo awaara naa.

Nibi iwode naa ti won pe akori e “Strengthen Democracy Through The Ballot” ni won ti so orisirisi oro nipa awon iwa ti won lodi si, eyi ti won lawon adari orileede yi n hu bii iwa ajebanu, ki ko oro ilu jo lona ti ko to, iwa jegudujera ati bee bee lo.

Ohun ti won lawon fe ni Ijoba awaarawa tooto, Eto eko to ye kooro, Eto ilera to dara, Aabo emi ati dukia, Ri ran ise agbe lowo atawon nnkan min in ti yoo se orileede yi lanfaani.

Nigba to n b’AWIKONKO soro lakoko iwode ipolongo naa, Komureedi Daniel to je Aare egbe Ogun Youth Alliance so pe asiko ti to fawon odo lati gba ijoba orileede Naijiria ninu idibo odun 2019 nitori pe awon ko le gba kawon adari to ti n dari orileede yi lati odun 1960 tun si maa tesiwaju.

Daniel so pe pataki egbe won ni lati bawon odo soro, ki won si gbawon nimonran lati jade dupo to ba wun won nidi oselu, tawon si setan lati gbaruku ti won, bo tile je pe egbe won kii se egbe oselu.

O ni “Bi e ba wo awon to n dari Naijiria lati odun 1960 si asiko ti mo fi n baa yin soro yi, e maa sakiyesi pe awon kan soso naa ni won wa nidi eto isejoba. Odo ni won wa nigba ti won bere, ki lo wa a de tawon naa ko le gba odo laaye lasiko yi. A o nii gba ki won je wa mo aye.

“Orileede Naijiria nilo afomo gidi, odo lo le se e, asiko si re e fawon odo lati gba ijoba lodun 2019. Mo ro awon odo orileede yi pe ki won loo gba kaadi idibo alalope (PVC) won ko too to asiko idibo, ki won si gbiyanju lati kopa ninu eto idibo naa.”

Oludari egbe Patroitic Allaince for National Development (PAND), Komureedi Moshood Muhammed nigba to n soro so pe bi awon odo ko ba fi le gba ijoba lodun 2019, o see se ka ja fun eto won wa, iyen revolution, nitori pe awon ko le gba ki won maa fi ojoola tafala. Bee lo so pe ko si nnkan to n je ojoola mo, nitori pe oni gan an ni ojoola ti won n so.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI