Ile ejo tu igbeyawo odun marun ka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 14, 2018

Ile ejo tu igbeyawo odun marun ka

Bo tile je pe baale ile tojo ori e o tii ju odun mokanlelogbon (31), Mutairu Afeez ko fara mo bi iyawo e ti won ti n ba ara won bo lati odun marun seyin, Kuburat Ishola Afeez se so pe ki ile ejo tu won ka, sibe ko si nnkan tile ejo le se lati tun je kife joba laarin won pada bii ti tele, ti won si fi ida ofin ile ejo tu won ka lojo Tosde ose to koja yi.
Iyaale ile naa, Kuburat, to ni odun mejidinlogbon (28) ni ojo ori oun lo mu ejo lo sile ejo koko-koko to wa ni Ake niluu Abeokuta pe ki won ba oun tu igbeyawo odun marun to ti wa laarin oun ati oko oun, nitori pe ara oun ko gba iya ajekudorogbo mo.
Kuburat so pe leyin toun gbe oko oun wa sile ejo, ti awon adajo ni kawon pada lo sile boya oro naa le yanju, toun si ro gbogbo iwa buruku owo oko oun yoo pada ro lara e, sibe bawon tun se kuro ni kootu lojo kejidinlogun osu to koja, se ni oko oun tun bere sii lu oun, de bi pe se lo ja oun sihoho omoluabi, tawon eeyan si n foun se yeye ladugbo.
Obinrin naa to je ko di mimo pe adugbo Soyoye loun n gbe niluu Abeokuta, toun si n ta oogun (Pharmacy) ni ko si nnkan toun se niwaju oko oun, to te e lorun ri, ti oun ko si le gba a mora mo, nitori naa ki onikaluku maa lo nilo o layo ati alaafia, ati pe oju orun to eye fo lai fi apa kan ara won.
Nigba to n soro, Baale ile naa Mutairu so pe iro nla ni Kuburat pa mo oun nitori pe oun kii fiya Kankan je, ati pe iya e ni ko fe e je ko ridi jokoo nile oko, nitori pe iwa toun ati iya e n hu ko te baba won, iye Baba Kubura lohun, ti ko si fowo sii pe kawon tuka.
O ni oun ko lu iyawo oun lojo yen, nnkan to loo sele ni pe, oloselu kan toun n ba sise lo ranse pe oun lori foonu pe kawon pade nikorita kan, ibe loun wa ti omo to wa laarin won, Aishat to je omodun meta ti sare wa ba oun, toun si n ba omo naa sere, gbara to so pe Kubura ri oun lo sare wa, to si n pariwo mo oun pe se loun fe e ji omo gbe.
O lariwo naa po debi tawon araadugbo gan an wo o pe ki lo n sele nitori pe se lo tun ranse pe iya e, ti won si wa n sepe foun, ti won tun n lu oun. sibe o loun ko setan lati ko Kubura gege bi iyawo nitori pe oun si nife e, sugbon toun faramo nnkan to n fe. Leyin o reyin lawon took-tiyawo naa fi Kurani (Quran) bura niwaju ile ejo pe ko si iro ninu oro tawon so
Awon adajo ile ejo naa, Oloye Akande O.O ati Onarebu Arabinrin Majekodunmi H.I nigba ti won n soro ti won bu enu ate lu iwa ti Mufutau n hu si iyawo to bimo kan soso fun, bee ni won gba a nimoran pe ko loo jawo.
NIgba tawon mejeeji bura tan ni Oloye Akande O.O to je aare ile ejo naa pase pe ile ejo tu igbeyawo won ka labe ofin, ti won si gbodo gba alaafia laaye laarin ilu. O ni ki Mufutau wa maa san egberun merin (4000) naira sile ejo naa losoosu fun itoju omo won, ati pe yato si eyi, awon mejeeji lo leto lati gbo bukata omo naa yala lori owo ileewe, oro ilera e, atawon nnkan min in tomo naa ba nilo.
Bakan naa lo tun pase pe igbakugba ti Mufutau ba fe e foju kan omo e lo le ri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI