LOBATAN: OGD DI ALAKOSO ETO IPOLONGO IDIBO AARE FUN ATIKU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 27, 2018

LOBATAN: OGD DI ALAKOSO ETO IPOLONGO IDIBO AARE FUN ATIKU

Igbakeji Aare teleri lorileede Naijiria, Atiku Abubakar ti kede gomina ana nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel gege bi alakoso eto ipolongo idibo aare (Director-General, Atiku Campaign Organization) lodun 2019.


Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo losan onii, ohun ta a gbo ni pe kii se pe Atiku Abubakar mon on yan Otunba Gbenga Daniel, iyen OGD gege bi alakoso eto ipolongo idibo e, sugbon awon akosile rere leka eto oselu lo fa a ti Atiku fi wo o pe oun gan an leni to le mu afojusun e lati di Aare orileede se.

Atiku ta a gbo pe abe asia egbe oselu PDP lo fe e gba jade lati dupo Aare naa la gbo pe gbogbo ona lo n wa lati de ipo naa, ti ko si fe e padanu lodun 2019 lo je ko ronu lati yan OGD.

Be o ba gbagbe, OGD gbe apoti idibo gege bi alaga apapo fegbe oselu PDP ninu eto idibo egbe naa to koja yi, sugbon to kowe sita pe oun ko se e mo, nitori naa, oun fi aaye sile fun Secondus lati tesiwaju gege bi alaga egbe naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI