AMOSUN, OLOTA LO S'ORILEEDE AUSTRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 29, 2018

AMOSUN, OLOTA LO S'ORILEEDE AUSTRIA

Bi e se n ka iroyin yi, ilu Vienna lorileede Austria ni Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ati Olota tiluu Ota, Oba Adeyemi AbdulKabir Obalanlege wa nibi ipade kan tawon omo egbe Oduduwa ni Vienna pelu ajosepo Diaspora Organization Europe (NIDOE, AUSTRIA CHAPTER) se agbekale e.


Gege bi Omoba Adeyemi Sulaiman Olusesi to je amugbalegbe Kabiyesi Obalanlege se fi to AWIKONKO leti, awon egbe naa ni won pe fiwe pe Kabiyesi sibi eto olojo meji naa gege bi Oba ojo naa.

Onii ojo kokandinlogbon ati ola ogbon ojo ni won fe e fi se eto ayeye Asa naa ti won pe ni 2018 Nigeria Cultural Festival.


Awon agbaagba nile Awori la gbo pe Alaaji Kehinde Saaka maa lewaju won tele Oba Adeyemi Obalanlege.

Lara awon ti yoo tun wa nibe ni Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun; Olowu tiluu Owu, Oba Adegboyega Dosunmu; Vivian N.R Okeke to je ajele orileede Naijiria si Austria atawon min in.

AWIKONKO gbo pe WELTMUSEUM, Vienna, Austria ni won ti n se eto naa, lara awon nnkan ti won si n safihan e ni Business Summit, Adire Exhibition, Egungun Display ati Africa Drums Exhibition.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI