E Gba Alaafia Ati Isokan Laaye - Enjinia Lawal - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 15, 2018

E Gba Alaafia Ati Isokan Laaye - Enjinia Lawal

Okan lara awon to n fe e jade dupo gomina ipinle Osun labe oselu All Progressives Congress (APC), Enjinia Ayoade Afolabi Lawal ti gbawon omo leyin Allah lamoran pe ki won maa gba alaafia ati isokan laaye ni gbogbo igba bi won ti pari aawe Ramadaani yi.


Enjinia Lawal lo soro yi ninu atejade to fi ki awon Musulumi fun ti ayeye odun Itunu Aawe jakejado agbaye, paapaa lorileede Naijiria, eyi to tun fi eda e ranse s'AWIKONKO.

Ninu atejade naa lo ti sapejuwe ayeye odun Itunu aawe gege bi okan lara awon opo to di esin Islam mu pelu bawon eeyan se n fi ara won jin fun Allah, paapaa lasiko aawe naa.

O tesiwaju pe kawon Musulumi lo anfaani asiko yi lati fi ife ati aanu han sawon alaini pelu ilana eko ti Ojise Olohun Muhammad fi ko won ninu Kuraani, ati pe ki won tun maa gba alaafia, eyi to je pataki eko Islam laaye laarin awon eeyan lagbegbe won.

Bakan naa lo ki gbogbo awon Oba Alade kaakiri ipinle Osun fun ti ayeye odun Itunu Aawe.

Bee lo gboriyin gun Gomina ipinle naa, Rauf Aregbesola atawon alabasise po e, to si tun gbadura fun ife, alaafia, isokan ati ilosiwaju orileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI