IDIBO 2019: KASAMU ATI OGD DI ORE APAPANDODO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 12, 2018

IDIBO 2019: KASAMU ATI OGD DI ORE APAPANDODO


Opo awon ti won gbo nipa nnkan to sele laarin awon agba oloselu ipinle Ogun meji nni, Otunba Gbenga Daniel tawon eeyan tun n pe ni OGD ati Seneto Buruji Kasamu ti won joo je omo egbe oselu alatako, iyen PDP ni won ko tii le so ibi ti ore apapandodo ti won de lose to koja yi niluu Abuja yoo tun pada ja si.

Bi e ba mo nnkan to n lo nipinle Ogun daadaa, paapaa ninu egbe oselu PDP tawon mejeeji yi wa, e o mo pe o ti le lodun mewaa bayii ti Kasamu ati OGD ti keyin sira won, ti won ko si gba tira won, paapaa nipa ti owo ti won ni Aare ana, Goodluck Jonathan gbe sile fun ipolongo lodun 2015, ti won so pe OGD ko o sapo.

Lose to koja niroyin awon mejeeji yi tun gbona min in yo, nigba ti won so pe Kasamu loo ki OGD nigba to gbo pe o ti niluu Abuja toun naa wa fun ti bi Atiku Abubakar se yan an gege bi alakoso eto ipolongo idibo Aare to fe e jade fun, bi won si se foju kan ara won, ni Kasamu sare di mon on pe oga oun ni Daniel.

Ko pe ti won soro die ni won lawon mejeeji pelu Seneto Ben Bruce wole loo jokoo soro fun bii wakati meta gbako, ki won too jade sita, ti won ko si so fenikeni nipa nnkan ti won loo so ninu yara ti won wo lo soro.

Alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun, Onarebu Sikirulai Ogundele nigba toun n soro nipa nnkan ipo ti egbe oselu PDP nipinle wa bayii, ati nnkan to ri si ibasepo to tun sese bere laarin OGD ati Kasamu, okunrin naa so pe ko si nnkan to le teyin ore apapandodo tawon mejeeji naa di yo.

Ogundele so pe gbogbo eeyan lo mo pe jaguda ati igi woroko to n da nnkan ru ni Buruji Kasamu nitori pe oun gan an lo fa iyapa to wa laarin omo egbe oselu PDP tele, ati pe egbe naa ti pada di eyokan soso bayii, pelu iranlowo ase tile ejo to ga julo lorileede yi, iyen Supreme court pa fawon.

Gbajumo oloselu naa je ko di mi mo pe oun ko gba pe Gbenga Daniel le tun pada ba Kasamu ti won n wa niluu Oyinbo se mo, latari bo se dabaru nnkan ninu egbe, sugbon to tun so pe oselu lasan lawon mejeeji n se funra won.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI