Onarebu Kayode Oladipupo to fe e lo soju ekun Abeokuta South, Constituency 1 lo soro naa lojo Tusde to koja yi pe ko ye ki ijoba apapo pa enu won mo lori ipaniyan ojoojumo to n ko awon araalu sinu ila-ilo, nitori naa ki won tete wa ona abayo ti yoo dopin iwa naa.
Ninu atejise to fi ranse s'AWIKONKO, Onarebu Oladipupo so pe oun mo pe ase wa lowo Aare Buhari lati dekun awon iwa buruku tawon Fulani daran-daran naa n hu kaakiri orileede, paapaa lagbegbe Guusu orileede yii.
O ni itiju nla lo ye ko je fun Aare Buhari pe asiko e ni ipaniyan yi n sele gege bi Aare orileede, ti ko si tii wa nnkan se sii latigba to ti depo naa lodun 2015.
Siwaju sii lo tun ran ijoba apapo leti pe ki won ranti awon ileri ti won se fawon omo Naijiria lasiko ipolongo idibo lodun 2015 nipa oro eto aabo, ati bi won se ni ko nii si itajesile lasiko ti won.
O ni pelu atejade ti Miyetti Allah fi sita pe awon Fulani to da emi awon araalu legbodo gbesan awon maalu won ti won ji ko salo ni, o ye ki won ti mo ibi ti oro naa ti wa, ki won si rii daju pe gbogbo awon to wa nidi ise ibi naa ni won mu bale.
Nigba to n menuba oga agba awon olopaa lorileede yi, iyen Ibrahim Idris, Onarebu Oladipupo so pe oun mo daju pe oga agba naa kaju e lati je ki eto aabo to pe ye wo Naijiria wa ni won se yan an sipo naa, nitori naa ki Aare Buhari pase fun un lati mu awon onise ibi naa, ki won si foju won han fawon araalu ko too di pe won fowo ofin mu won.
O wa gbawon omo Naijiria lamoran pe ki won ma se dekun lati maa gbadura fun orileede yi, nitori pe ko si nnkan meji to le dekun awon iwa bayii, bi ko se adura ojoojumo fun orileede ati paapaa fawon adari inu e.
No comments:
Post a Comment