Iwe Iroyin Alariya Oodua fee da Olubadan l’ola - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 28, 2018

Iwe Iroyin Alariya Oodua fee da Olubadan l’ola

Gbogbo eto lo ti fe e pari bayii fun ti ayeye idalola t'ileese iwe iroyin Alariya Oodua to gbajumo lorileede Naijiria, paapaa lawon orileede to sunmo Naijiria bii Cotonou ati ile Olominira Benin fe e se fun Olubadan tile Ibadan, Oba Salisu Adetunji to je Aje Ogunguniso kinni in.

Oyekunle Babarinde ati Oba Adetunji
Ojobo Tosde, ojo kerindinlogbon osu keje to n bo yi (Thursday, July 26th, 2018) ni ayeye naa fe e waye ni gbongan ayeye ti Mapo to wa niluu Ibadan, bere lati aago mewaa aaro.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yii, ohun ta a gbo ni pe Ogbeni Oyekunle Babarinde to je olootu iwe iroyin Alariya Oodua naa lo ko iwe itan kan ti won pe ni Yoruba Ni Tooto lati fi da Kabiyesi naa lola.

Bo tile je pe a ko tii gbo nipa idi ti olootu naa, Ogbeni Babarinde se pinnu lati f'iwe naa da Olubadan l’ola, sibe a gbo pe lati mu ki isokan ile Yoruba le tubo peregede sii, pelu bi Oba Salisu Adetunji se n fojoojumo wa bi alaafia ati isokan yoo tun se pada wo ile Yoruba wa, ti ko si nii si oro eleyameya mo niwe na wa fun.

Iwe itan naa, Yoruba Ni Tooto la gbo pe Ogbeni Babakunle Oyerinde ko ni iranti awon akoni to ti lo bii iya Olubadan tiluu Ibadan; Oloogbe Arabinrin HID Awolowo; iya Oloye Olusegun Obasanjo; iya Asiwaju Bola Ahmed Tinubu; iya Ogbeni Rauf Aregbesola; iya Ogbeni Femi Adesina to je agbenuso fun Aare Muhammad Buhari.

Awon to ku ni; iya Ooni tile Ile-Ife, Oba Enitan Ogunwusi; iya Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi; iya igbakeji gomina ipinle Osun tele, Seneto Iyiola Omisore ati iya Aare Ona Kakanfo, Otunba Gani Adams, eni to tun je olori egbe OPC.

Ohun ta a gbo ni pe awon Ojogbon kaakiri ileewe giga tawon olukoni, iyen Federal Colleges of Education kaakiri orileede Naijiria, to fi mo awon Ojogbon to mo nipa isedale ati itan Yoruba fowo si ni iwe itan YORUBA NI TOOTO yi je.

Iwe Ipe, I.V
Omowe S. M. Raji to je aare ana f’egbe awon olukoni nileewe olukoni, NCE lorileede yi lo bu owo lu iwe yi lodun to koja, iyen ni gbara to se ayeye finni-finni nipa e, to si jeri sii pe oun ko tii ri iwe itan Yoruba bii ti Yoruba Ni Tooto ri, ntiori pe o kun fun ise imo ijinle.

Gomina Abiola Ajimobi tipinle Oyo la gbo pe yoo gbawon eeyan l’alejo lojo naa, nigba ti Seneto Rasheed Ladoja to je gomina tele nipinle naa ni yoo je gege bi alaga ojo naa.

Oloye Lekan Alabi to je Agbaakin ile Ibadan  ati Ojogbon Duro Adeleke ti fasiti Ibadan, iyen UI ni yoo dawon alejo lekoo, nigba ti Dokita (Omowe) S. M. Raji yoo fiwe naa han. Onimo-ero Seyi Makinde ni yoo fiwe Yoruba Ni Tooto l’ole, nigba ti Agbenuso Aare Buhari, Ogbeni Femi Adeshina yoo so nipa iwe itan naa.

Bakan naa ni Alaaji Lai Muhammed to je Minisita foro Asa ati awon ibi igbafe lorileede yi ni yoo je alejo pataki lojo naa.

Yato si awon Ojogbon leka eto eko lorileeede yi, awon oloselu atawon agbaagba to le so nipa itan ile Yoruba naa bu owo lu iwe Yoruba Ni Tooto, ti won si ti n gbaradi fun ojo kerindinlogbon osu keje to n bo yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI