Iyawo mi ti l'oko min in leyin osu kan ta a ja, e tu wa ka. Mo fe e gba omo mi - Akeem - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 25, 2018

Iyawo mi ti l'oko min in leyin osu kan ta a ja, e tu wa ka. Mo fe e gba omo mi - Akeem

To ba di ojo kesan an osu to m bo ti Ogbeni Akeem Wahab ko ba mu anti e to so pe won le ba oun toju omo to fe e gba lowo iyawo e dani, o see se ki ile ejo koko-koko to fikale sadugbo Ake Abeokuta ma pada gbe omo naa fun un, ati pe bi obinrin naa ba tun je eni ti ko karamasiki ojo iwaju omo, ile ejo naa tun le ma gbe omo e, Basit naa fun un.

Bo tile je pe akoko re e ti toko-tiyawa naa yoo ro ejo won ni kootu, sugbon lojo Tusde ose to koja ni Baale ile naa, Ogbeni Akeem to ni moto boosi akero loun n wa so pe ko seni to le be oun pe koun gba iyawo oun, Bilikisu pada pelu bo ti se yan agbere laayo, toun si ti ka a ko pe lu orisirisi okunrin lai moye igba.

Akeem ni ko tii ju osu kan lo tawon ni gbolohun aso kekere ninu ile, to di pe Bilikisu ko eru e jade, to si je pe se ni okunrin min in lo gba ile fun ladugbo Oke-Lantoro niluu Abeokuta.

O so pe ore e oun kan to n gbe inu ile ti ale gba funyawo oun lo tu asiri naa soun lowo, toun si loo fidi e mule nigba toun de be, iyen lodun meje seyin.

Baale ile to so pe oun ko niya ati baba mo ni, nnkan to tun n je kayeefi ati iberu foun ni pe latigba toun ti so pe oun fe gba omo oun niyawon oun ti n lepa emi oun, to je pe Olorun lo si n ko oun yi titi dasiko toun fi n soro. Bee lo so pe bi moto toun n wa ko ba ti e foun laaye lati bojuto omo oun, anti oun wa nitosi to le maa ba oun toju e daadaa, bo tile je pe ko si nile ejo lati farahan nitori pe ara e ko ya.

Bilikisu ni ti e so pe iro patapata ni oko oun n pa pe oun ni egbon kan to le ba a toju omo nitori pe anti e to n so yen ti dagba, ise alajapa lo si n se, ti kii raaye lati bojuto omo to bi ninu ara e depodepo pe yoo toju omolomo bi omo oun.

O ni kile ejo ma se gbo awon awijare iro to n so lenu nitori pe ijapa gan an ni oko oun, ati pe anti e to so pe ara e ko ya yen wa nibi to ti n sise ajapa nitori ola (Wesde) je ojo oja Kuto ni ko se le wa.

Bee lo tun so pe oun ko le gba ki won je ki omo oun di eni to n kiri oja kaakiri igboro, nitori pe ojo ola e lo se pataki soun, toun si setan lati ran lo sile eko titi ti yoo fi jade.

Baba iyawo nigba toun n so tenu e so pe looto lo je pe Akeem lo ni omo, toun ko si so pe ko ma gba omo e, sugbon kii raaye fenikeni latari ise de-toru-toru to n se.

Eyi gan lo mu ki Aare ile ejo naa, Oloye Akande O. O ati igbakeji e, Onarebu Arabinrin Majekodunmi H. I so pe ayafi tawon ba foju kan anti naa ti Akeem n so, kawon too le sedajo won, nitori naa ko rii daju pe anti e wa nikale to ba di ojo kesan an, osu keje odun yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI