Ko si omo eyin Yayi to loo segbe oselu ADC o – Odunaro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 26, 2018

Ko si omo eyin Yayi to loo segbe oselu ADC o – Odunaro

Lai pe yi niroyin kan n lo kaakiri orileede yi pe awon omo eyin Seneto to n soju ekun Lagos West nile igbimo asofin agba niluu Abuja, Seneto Olamilekan Adeola tawon eeyan tun mo si Yayi ti lo segbe oselu ADC lati loo satileyin fun Gboyega Nasiru Isiaka.

Ohun ta a gbo ni pe ko din legberun mewaa awon eyin Seneto Yayi ni won so pe awon ti setan lati tele GNI ninu idibo odun 2019 to n bo lona, ati pe won ko tii mo ipinu Seneto Yayi, boya yoo si dije gege bii gomina ipinle Ogun, ko si too pe ju, kawon tete loo satileyin fun GNI.

Agbenuso Seneto naa nipinle Ogun, Oloye Kayode Odunaro nigba to n fidi oro naa mule lojo Sande to koja yi, o so pe aheso to jinna si otito patapata niroyin eleje naa, ati pe lati fi da egbe Yayi ru ni.

Oloye Odunaro so pe bo tile je looto lawon kan kuro leyin Seneto yayi lati loo satileyin fun GNI, sugbon awon to lo naa lawon olote ti won kuro legbe oselu PDP, to si je pe owo ati bi won yoo se da egbe ru ni won n wa kaakiri.

Bee lo tun so pe lara awon die ti won kuro naa lawon ti won ko rowo mu leyin ipade gbogboogbo egbe oselu APC ti won se lai pe yi lawon eeyan naa, ti won si fe gba okiki tipatipa.

Okunrin naa tun so pe gege bi oga gbogbo won, oun ko tii pase pe kenikeni kuro leyin Yayi, ati pe boun ko ba ti e ni satileyin fun Seneto Yayi mo, se loun yoo kuku kowe fipo oselu sile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI