OKO MI FE E PA MI, MI O FE MO – IYAALE ILE PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 9, 2018

OKO MI FE E PA MI, MI O FE MO – IYAALE ILE PARIWO SITA

Se lawon to wa ni kootu kokokoko to wa ni Ake niluu Abeokuta fe e le maa ba iyaale ile kan, Arabinrin Adijat Balogun sunkun nigba to n ro ejo oko e niwaju adajo pe o ti fe e lu oun pa sinu ile, ati pe yato pe oun sa kuro nile fun un lo sodo mama oun, se loko oun tun wa a ka oun mobe, to si fi ada sa oun.

Ko si nnkan to je kawon eeyan fe e ba obinrin naa sunkun, bi ko se tawon foto to fi se eri niwaju ileejo to ko sile, tawon eeyan si ri bi oko e, Ogbeni Tajudeen se sa a  yannayanna leyin to luu tan.

Bo tile je pe kii se akoko re e tawon mejeeji yoo soro nile ejo, nitori ti adajo ti so pe kawon mejeeji pada loo sile lati woo bo ya oro won le pari, sibe Iyaale ile naa so pe “Bo tile je pe oko mi fe ko pari, sugbon mi o le pada sodo e mo, nitori pe mi o se tan lati ku losan gangan.

“O ti le lodun kan ti mo ti sa kuro lodo e, ti mo lo n gbe lodo mama mi ni adugbo Itoku, sibe se lo tun maa wa lu mi mo be, to maa da gbogbo igba buredi ti mo n ta nu, bee ni kii tun n beere awon omo merin ti mo bi fun un, ti ko si ni fun won lowo ounje.

“Lojo kan, se lo wa sile ti mo n gbe lodo mama mi, to wa a lu mi mobe, nibe lo ti fi ada sa mi, to je pe osibitu ni mo laju si, ti mo si padanu eje pupo, sibe ko yoju lati wa a wo alaafia mi. oluwa mi, oro e ti su mi, e saanu mi. A lo si tesan Oke-Itoku lati loo fejo sun, awon olopaa ti mole fun bii ose kan, leyin e ni won gbe e lo si Kootu Isabo, sibe emi ni mo tun be won pe ki won ma ran lo sewon nitori pe baba awon omo mi ni.”

Ibi ti Adijat soro de re e ti Adajo fi ni ki oko e, Tajudeen naa soro, nnkan to so ni pe “Alaigbonran niyawo mi, aigbonran e lo si fa a ki n maa lu ni gbogbo igba. Se e ri lojo to so pe mo fi ada sa oun yi, mo lo sile won to n gbe, bo se ri mi lo so ija lu mi, to tun fo gilaasi taisi (taxi) ti mo wa n wa, ibe ni inu ti bi mi, ti mo fi yo ada sii.

“Iro lo pa pe mi o kii fawon omo mi lowo ounje, mo maa n fun won, awon omo mi ni mo si maa n pe lori foonu lati fun won lowo ounje. Sugbon latigba ti moto mi ti baje ni mi o ti fun won lowo mo.”

Nigba to n soro, Aare ile ejo naa Oloye Akande O. O ati igbakeji e, Arabinrin Majekodunmi H. I bu enu ate lu iwa ti Tajudeen hu, won si je ko mo pe iwa odaju lo hu yen. Bee ni won pase pe ki Tajudeen koko loo wa owo ounje fawon omo e ko too di ojo ketala osu yi, iyen ojo Wesde otunla to n bo yi, ki won too tesiwaju ninu ejo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI