Tisa ko oko e sile leyin odun merinla ti won ti fera won - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 25, 2018

Tisa ko oko e sile leyin odun merinla ti won ti fera won


Se lawon ero to wa ni kootu koko-koko Ake Abeokuta la enu won sile ti won ko le pa a de nigba ti won ri okan lara awon agba Tisa nile eko fasiti Federal University of Agriculture Abeokuta, FUNAAB to n be adajo pe ko ba oun tu igbeyawo olodun merinla to wa laarin oun ati oko oun ka.

Bo tile je pe kii se akoko re e ti iyaale ile naa, Arabinrin Mojisola Olanike Adegunwa maa koko fara han nile ejo naa, ko too di pe adajo fa iwe igbeyawo to so oun ati oko e, Alaaji Saola Adetona Adegunwa ya.

Ohun ta a gbo ni pe eemeji otooto ni ile ejo naa ti fiwe pe Alaaji Saola Adegunwa pe ko yoju lati wa so tenu e, ati pe o le see se ko je pe se niyawo e, Mojisola wa a paro mon on, sugbon ti Baale ile naa ko jale, ti ko yoju.

Mojisola nigba to n fi bibeli bura lojo Tusde ose to koja yi pe oun ko nii paro pelu gbogbo nnkan toun fe e so, so pe nnkan toun fe ni pe kawon omo meji toun bi fun oko oun wa lodo oun lati maa toju won, o ni aaye wa fun Alaaji Adegunwa lati wa maa yoju sawon omo naa nigba to ba wun.

Iyaale ile eni odun metadinlaadota (47) naa, to so pe igbeyawo ibile (traditional wedding) lawon se je ko di mi mo pe ko se dandan ki oko oun gbo bukata lori awon omo naa nitori pe agbara oun gbe e lati toju won, sugbon to ba wun un lati da si bukata awon omo naa, ko si nnkan to buru nibe, nitori pe oun ko le fi tipa muu.

Nigba to n gbe idajo kale, Oloye Akande O. O so pe pelu bi Alaaji Adegunwa ko se yoju lemeeji otooto ti ofin la sile lati fiwe pe eni ti won ba fesun kan pe ko yoju lati wa a so tenu e, o fi han daju pe Alaaji ko nife si igbeyawo naa mo, to si je gege bi eri lati di mu fawon.

O tu igbeyawo naa ka pelu pelu ase pe awon mejeeji ko gbodo ba ara won fa wahala, ti won gbodo gba alaafia laaye, bee lo pase pe awon mejeeji lo letoo lati gbo bukata lori awon mejeeji naa, iyen Adetomiwa Adegunwa, omodun mokanla ati Ademide Adegunwa toun je omodun mesan an.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI