WON FESUN APAAYAN KAN OMO ILE IGBIMO ASOFIN IPINLE OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 9, 2018

WON FESUN APAAYAN KAN OMO ILE IGBIMO ASOFIN IPINLE OGUN...Lesekese lo pariwo sita pe oun ko mo won ri

Ko tii seni to le so ibi ti oro naa yoo ja si bayii lori bi awon gendekunrin ti won je omo egbe okunkun merin kan ti won furasi pe won pa okunrin kan ti won n pe ni Arsenal-Nice niluu Sagamu lai pe yii, to si je pe asiko ti won n ka boroboro ni won so fawon olopaa SARS pe okan lara awon omo ile igbimo asofin nipinle Ogun to gbajumo daadaa, iyen Onarebu Yinka Mafe to soju ekun Sagamu lo ran won ni se.

Awon merin naa, Olushola Adedeji; Olusegun Olalekan ti inagije n je Musket; Azeez ti won tun n pe ni Anene ati Abolore ti won tun pe oun naa ni A.B la gbo pe won wa lara awon ti Onarebu Mafe n san owo osu fun.

Ojo Tosde ose to lo lohun la gbo pe asiri won tu leyin ti enikan ti won foruko bo lasiri loo tawon olopaa lolobo pe oun mo awon to pa Arsenal-Nice, ati pe awon naa ni won n da alaafia Sagamu laamu, ti won ko je kawon araalu sun oorun asundokan.

Esun yi lo mu kawon olopaa ZIS to wa ni Obada-Oko niluu Abeokuta gbera lo siluu Sagamu lati loo ko won, ti won si bere sii jewo fawon olopaa pe oloselu kan lo ran won.

Nigba to m fidi isele naa mule, Dolapo Badmus to je alukoro olopaa Zone 2 niluu Eko so pe looto lawon odaran naa ti jewo, ti won si tun je ko ye won pe Onarebu kan to gbajumo daadaa lo ran won nise, sugbon ti iwadii si n lo lowo.

Lesekese tiroyin naa ti te Mafe funra e lowo lo ti so pe iro lawon eeyan naa n pa, ati pe kawon olopaa tete gbe ejo naa lo si kootu, koun si le tete wa a jeri gbe ara oun ni kootu pelu boun tun se je agbejoro.

Siwaju sii ninu iroyin min naa lose to koja yi la gbo pe Gomina Amosun ran Onarebu Yinka Mafe pe ko lewaju awon janduku lati loo fiya je Onarebu Adebiyi Adeleye toun n soju ekun Remo North latari pe o kuro ninu egbe oselu APC lo si egbe oselu PDP.

Onarebu Adebiyi la gbo pe o bu enu ate lu bi Gomina Amosun ko se sise de ekun to n soju fun, paapaa ilu Isara to ti wa, to je pe awon ibomin in lo n sise sii, paapaa ilu Abeokuta, ti ko si boju wo iya tawon eeyan ekun naa n je.

Ojo Monde to koja ni Onarebu Adeleye pe ipade awon oniroyin, nibi to ti so pe Onarebu Yinka Mafe pelu iranlowo Gomina Amosun n dunkoko iku moun latari boun se fi egbe oselu APC sile lo segbe oselu PDP, bee lo tun so pe won fesun kan oun pe oun sagbateru awon omo egbe okunkun.

Eyi gan an la gbo pe o bi Amosun ninu, ko da ti won tun loo fi SARS gbe nile e laaro kutu ojo Tusde, to si je pe ojo keji ni won fi sile lahamo awon SARS to wa ni Magbon, Abeokuta.

O ni oun ko soro pe won yo oruko oun kuro ninu iwe eto ti won se lati fi gbe ade le Odemo tiluu Isara Remo lori losu to koja, nibe naa ni woj tun ti ran awon toogi pe ko lu oun, ti won si tun ja oun sihoho omoluabi.

Nigba to n b'AWIKONKO soro lojo Wesde ose to koja ninu ofiisi e, alaga egbe oselu PDP nipinle, Onarebu Sikirulai Ogundele bu enu ate lu iwa ti Amosun hu naa, to si so pe onikaluku lo ni eto lati darapo mo egbe oselu to ba wuu, paapaa ti egbe oselu tiru eni bee ba wa ti ko si te e lorun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI