E MA JE KI OMI GBE WA LO O: BALOGUN OF IJAYE RAWO EBE SI GOMINA AMOSUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 5, 2018

E MA JE KI OMI GBE WA LO O: BALOGUN OF IJAYE RAWO EBE SI GOMINA AMOSUN


Balogun ilu Ijaye, Oloye Ganiyu Babayeju ti ke gbajare si Gomina Ibikunle Amosun pe ko wa a fi oju aanu wo awon ara oja Gbangba to wa lagbegbe Iyana-Mosuari, Abeokuta latari ojo olojo meta arooroda to ro lai pe yi.

Oloye Ganiyu Babayeju, eni to tun je Aare ile Egba lo rawo ebe naa lai pe yi pe ojo to ro lojo Fraide si Sande to koja yi ti ba opolopo nkan je ninu oja naa, ati awon ile to wa nitosi e latari bi odo to gba Gbangba naa koja se kun akunwosile.

Fawon to ba mo oja Gbangba naa daadaa, won a mo pe odo kan gba aarin oja naa koja. Odo yi lo san wa lati awon agbegbe bii Idi-Aba, Abiola-Way, Adatan, Isale-Abetu to fi mo Lantoro, to si je pe oja naa ni won ti pade.

Ojo olojo meta to ro naa la gbo pe o ya bo biriiji Gbangba yii, to si ba awon apa kan legbe biriiji naa je, ko da a, to fi mo awon soobu to wa nitosi e la gbo pe ojo agbara ya bo, to si ba opolopo awon oja to wa ninu awon soobu naa je koja siso.

Nigba to n b'AWIKONKO soro, Oloye Ganiyu so pe edun okan lo je foun nigba ti oja naa bere, ati pe awon eleyinju-aanu toro naa soju won ni won gbiyanju lati Dari agbara naa sibomin in sugbon ti ipa won ko maa.

O ni gbogbo bawon se n gbiyanju lati dekun oniyale, agbara ya soobu lo n ja si pabo fawon. O wa rawo ebe si Komisana lori oro ise ati Gomina Amosun pe ki won tete wa a bawon wa nnkan se sii.

Nigba toun naa n soro, iyaloja naa, Oloye (Alaaja) Tekobo so pe odo to san koja Gbangba naa nilo pe ki won fe e (expand) sii, ko le gba agbara to po, to ba fe e koja nibe lai ni idiwo.

Alaaja Tekobo so pe awon iyepe tawon ko sinu awon baagi simenti, ayo tawon fi n di oju ona yi, fungba die tijoba yoo fi wa bawon tun un se daadaa ni, ati pe to ba fi maa to igba die si asiko yi, o see se ki oja ona naa ma se e gba mo fun moto, okada tabi awon to n fese rin koja nibe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI