EGBE OSELU ACCORD GBARADA NILUU ABEOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 27, 2018

EGBE OSELU ACCORD GBARADA NILUU ABEOKUTA

Lojo Wesde to koja yi ni egbe oselu ACCORD nipinle Ogun gbarada lasiko ipolongo imurasile idibo odun 2019, nibi ti won ti fi adije sipo gomina ti won fe e fa kale han fawon omo egbe atawon araalu, ki won le mo eni ti won yoo dibo fun.


Bo tile je pe gbogbo ona la gbo pe Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun n gba lati ma je legbe oselu min in dide mo nipinle Ogun, nitori ti won so pe gbogbo egbe oselu ti won ba fe e se eto ipolongo tabi ipade gbogboogbo won lawon agbegbe to je tijoba ni gomina naa kii gba won laaye lati se e.


Iwaju gbongan atijo, iyen Centenary Hall to wa ladojuko Aafin Alake tile Egba ni eto gbogboogbo egbe naa waye, nibi ti won ti fi Ogbeni Tope Tokoya to ti figba kan ri je alaga ijoba ibile Odogbolu han gege bi adije sipo gomina atawon adije sipo omo ile igbimo asoju-sofin ipinle Ogun lodun 2019.


Opo awon omo ipinle Ogun, paapaa awon araalu Abeokuta ni won filu ati ijo gba egbe oselu ACCORD naa pe awon gan an lawon n fe lodun 2019, nitori pe egbe oselu APC ti su awon, ati pe gbogbo ileri tegbe APC se fawon araalu ni won ko mu se.


AWIKONKO gbo pe asiko tawon araalu naa n fi idunnu won han segbe oselu ACCORD ni won so pe gomina Ibikunle Amosun koja lati loo wo bawon arralu se gba ti won sii, itiju ni won loo je fun nigba ti won bere sii korin buu.


Ibinu ni won ni gomina Amosun fi sare loo ba Alake tile Egba, Oba Michael Adedotun Aremu Gbadebo pe ko ye ko gba awon eeyan naa laaye lati se ipolongo niwaju ita aafin e, sugbon ti won ni Alake so fun un pe ko si nnkan toun fe e se sii nitori toun kii se oloselu.


Bo tile je pe AWIKONKO ko si nibe, sugbon lara awon to gbe iroyin naa si wa leti je ko ye wa pe to ba see se ki won ju okuta lu gomina Amosun ni, won a so o, sugbon orin eebu ti won ko fun gomina naa ni ko le tete gbagbe laye e.


Nigba to n soro nibi eto naa, Tokoya so pe asiko ti to fun egbe oselu min in lati gbajoba kuro lowo awon to n isejoba lowo yi, nitori pe egbe won ti setan lati yo ipinle Ogun kuro l'oko eru.

Saaju asiko yi nigba ti Tope Tokoya n bawon oniroyin ipinle Ogun soro ninu gbongan won to wa ni Iwe-Irohin, Abeokuta, o seleri pe ijoba oun ko nii ye awon ise gomina Amosun wo, tawon araalu ba dibo foun.

O ni nnkan meje loun fe e sise le lori, lara e si ni Eto ilera, ise agbe, ise fawon odo ati igbelaruge ere idaraya pelu eto ile gbibe atawon min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI