EGBE ONIROYIN ORI ERO AYELUJARA, OMPAN LALEHU NIPINLE OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 27, 2018

EGBE ONIROYIN ORI ERO AYELUJARA, OMPAN LALEHU NIPINLE OGUN

Se ni idunnu subu lu ayo awon oniroyin, paapaa awon oniroyin ori ero ayelujara tipinle Ogun nigba ti alaga egbe akoroyin ori ero ayelujara ti won pe ni OMPAN kede pe kipinle Ogun naa da egbe sile labe egbe akoroyin lapapoo, Nigeria Union of Journalists (NUJ).


Lojo Tosde to koja yi igbakeji alaga egbe Online Media Practitioners of Nigeria, OMPAN, Komureedi Peter Jones Ailuorio pelu ifowosowopo alaga egbe akoroyin nipinle Ogun, Komureedi Oluwole Sokunbi bura fawon oloye fidihe ti yoo tuko egbe naa fun odun kan gbako lasiko ti won fi egbe naa le le.

Awon oloye naa ni Komureedi Kayode Akin-Samuel, oludasile Falcon Times to je alaga; Komureedi Michael Adesanya, akoroyin City Voice to je igbakeji alaga; Komureedi Michael-Azeez Ogunsiji, akoroyin fun Saharaweekly to je akowe; Komureedi John Izabi, oludasile Newsflakes toun je PRO.

Awon to ku ni: Komureedi (Arabinrin) Shola Ajibike, akoroyin Gateway Mail, to je akapo owo; Komureedi Adejola Crown oludasile Tropic Reporters to je Welfare officer; ati Komureedi Gbenga Oladipupo toun je oludasile iroyin Awikonko toun je akowe owo.


Lara awon omo egbe naa ni Ogbeni Sanusi Lateef je oludasile News World Prime; Ogbeni Abiodun Lawal to je oludasile Ogun Today ati Nifemi Gbangbayan toun je akoroyin Tropic Reporters.

Nigba to n ki awon oloye egbe tuntun naa ku oriire, alaga egbe akoroyin nipinle Ogun, Komureedi Oluwole Sokunbi so pe kii se pe ki won lo anfaani naa lati fi si ipo naa lo, bi ko se lati gbe ise akoroyin laruge nipa awon iroyin ti won gbe jade.

Sokunbi tenumon on pe kawon eeyan naa finu han ara won, ki won ma si se fi nkankan pamo fun ara won, iyen transparency, eyi ti yoo gbe ipinu ati ilepa egbe naa laruge, paapaa nipinle Ogun.

Ninu oro ti e, igbakeji alaga egbe naa lapapo, Komureedi Peter Jones je ko di mimo pe, kawon oloye tabi omo egbe naa ma se ri egbe naa gege bi egbe isokan (union), bi ko se eka egbe ti won ya soto lara egbe akoroyin, iyen NUJ, ti won si gbodo maa bowo fun egbe NUJ to je baba won nitori pea be e ni won wa.

O tenumon on pe ki won rii daju pe won n gbe ise naa laruge ni gbogbo igba, lai fi oro oselu tabi eleyameya se, bee lo gbawon oloye tuntun naa lamoran pe ki won lo anfaani ipo naa lati gbe oruko egbe naa laruge, ki won si gba alaafia laaye ki osu mejila ti idibo miran yoo waye.

Ninu oro idupe ti e, alaga tuntun fegbe tuntun naa, Komureedi Kayode Akin-Samuel dupe lowo alaga egbe naa lapapo, paapaa alaga egbe akoroyin nipinle Ogun fun ise takun-takun ti won n se lati gbe ise oniroyin laruge.

O seleri pe oun yoo lo agbara oun lati je ki egbe naa fese mule daadaa, toun yoo si je ki ibasepo to dan monran wa laarin awon oloye egbe naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI